Yẹmi My Lover sọrọ sawọn oṣere ẹgbẹ ẹ nitori Tinubu

Aderohunmu Kazeem

Ninu fidio kan to farabalẹ ṣe, to ti wa nita bayii, ni ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba, Yẹmi My Lover, ti kọ lu awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, paapaa awọn to ṣe oriṣiiriṣi fidio lati fi ta ko bi wọn ti ṣe pa awọn ọdọ kan nipakupa ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, lọsẹ to kọja, ti wọn si sọ pe iṣẹlẹ naa lọwọ Asiwaju Bọla Tinubu ninu.

Yẹmi Ayebọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Yẹmi My  Lover, sọ pe ohun itiju lo jẹ nigba ti oun ri bi awọn ẹlẹgbẹ oun ti wọn ti jẹ ninu owo Bọla Tinubu daadaa, ti ọkunrin oloṣelu naa ti ran lọwọ lọpọ igba, ti wọn jade bayii, ti wọn gbe kamẹra, ti wọn n sunkun yọbọ, tawọn naa pẹlu awọn to n sọrọ odi si Bọla Tinubu lai wadii bọrọ ṣe jẹ gan-an lori ẹni to ran awọn ṣoja jade lati kọ lu awọn to ṣewọde ni Lẹkki.

Ayebọ sọ pe, “Ipa ti awọn oṣere wa gan-an ko lo dun mi ju, bẹẹ lo jọ mi loju gidi, bi wọn ṣe n sunkun ofo yẹn, niṣe ni inu buruku n bi mi, ṣe ọfọ ṣẹ wọn ni? Nitori ẹni ti ọfọ ba ṣẹ kọ lo maa gbe foonu tabi kamẹra ti a bẹrẹ si i ya ara ẹ. Loju temi, ẹkun ofo ti wọn n sun kiri yẹn, ohun ti wọn n sọ fun araalu ni pe Bọla Tinubu ti balu jẹ, Bọla Tinubu ti paayan rẹpẹtẹ, o ti da wahala silẹ. Ti ẹ ko ba mọ, ohun  ti ẹ n sọ fun araalu niyẹn. Ọrọ yẹn gan-an lawọn kan n tẹle, ti wọn n fọle kiri, abi ẹ waa gba mi! Bi wọn ṣe n jo ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC, bẹẹ ni wọn jo awọn mọto BRT naa.

“Gbogbo ẹyin onitiata ti ẹ sọ ọrọ to delẹ yii di sinima, ti ẹ n ya ara yin, o ku diẹ kaato fun yin o. Niṣe loju ti mi gidigidi fun yin. Ọkan tiẹ tun sọ pe oun kabaamọ pe oun polongo ibo fun APC, ẹ ba mi bi i pe ṣe iṣẹ ọfẹ lo ṣe ni? Ṣe wọn waa wọ ọ nile ẹ ni? Ẹ tun ba mi bi i pe ṣe o pẹlu awọn to dibo ni, abi ṣe ko gba owo ipolongo ibo to ṣe lọwọ Tinubu ni, bẹẹ gbogbo eeyan pata lo n wo wa, ohun ti awa oṣere ba ṣe tabi sọ lawọn eeyan yoo tẹle.”

Yẹmi fi kun un pe oun naa ko fara mọ awọn ẹṣọ agbofinro SARS, ati pe oun ko sọ pe ohun ti ijọba n ṣe dara, ṣugbọn bi wọn ti ṣe fẹẹ gbogun ti Bọla Tinubu nilẹ Yoruba yii, aṣiṣe nla gbaa ni.

O ni ti gbogbo eeyan ba tiẹ n ṣe e, ko yẹ awọn ti awọn jẹ oṣere, bo tilẹ jẹ pe lara awọn eeyan ti ọkunrin naa ti sọ di eeyan nla nidii oṣelu ni wọn n wa iṣubu ẹ kiri bayii.

Yẹmi Ayebọ ti pariwo pe ki wọn ma pa a gẹgẹ bi wọn ṣe pa Awolọwọ ati Abiọla, nitori pe oun ni Yoruba n wo loju loni-in.

11 thoughts on “Yẹmi My Lover sọrọ sawọn oṣere ẹgbẹ ẹ nitori Tinubu

  1. Yemi my lover a bi kini won npe idiot gidi niyin abajo eo se rogo ninu ise tiata.a bi protest yen se o fara jo awokun film Indian ti ense Kiri.sir nkan nse yin boya eyin gan lewo aso soja lopa awon Omo olomo.olorun yio pa tiyin laipe boya eowa sunkun ofo abi Yoruba yio wa bayin sofo .useless actor.

  2. Hmmm mr yemi i dnt expect dis frm u,der is no different frm ur speech nd d speech of our president,lyf of d innocent bcam noting to u dats y u nevr dare speak of it,after u said ur fellow actors nd actress eat frm his money, nd so even if dey eat frm it does dat mean if tins is goin wrong dey should nt talk,dats d betrayal we are talking of o,dose wo sold der tribes der friends der family fr money,ole omo ale yoruba, senseless fool onijekuje,alailoto lenu

  3. She nitori ki Tinubu le ran o lowo lo n fii so gbogbo iredodi Oro won yii.O mo otito sugbon o so,afaimo ki o ma ku sigbo ika .Awon to won fehunnu won han si ipakupa you,won Peri ju o lo.

Leave a Reply