Yẹmi Ọṣinbajo, ṣi ni aayo ninu awọn to fẹẹ dupo aarẹ – Ojudu

 

Saka Monisọla

Oludamọran pataki si Aarẹ, Muhammadu Buhari lori ọrọ oṣelu, Babafẹmi Ojudu, ti ṣeleri lati pada si oko dipo ki o ti Bọla Tinubu lẹyin lori erongba rẹ lati di aarẹ.

Ojudu sọ ọrọ yii di mimọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu oniroyin awọn alafẹ kan, Chude Jideonwo lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ yii.

O ni Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, lo ṣi n jẹ aayo oun ninu awọn to n du ipo aarẹ.

Nigba ti akọroyin naa bi i boya o le yi ọkan rẹ pada ti Buhari ba ti Tinubu lẹyin, Ojudu ni “Laelae. Ẹ gba bẹẹ, ẹ kọ ọ kalẹ lonii, oko ni ma a pada si ti mo ba gbọ pe Aṣiwaju Bọla Tinubu ni Buhari ṣatilẹyin fun lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023. Ti mi o ba nigbagbọ ninu eeyan kan, mi o le ṣiṣẹ fun un iru ẹni bẹẹ tabi ki n ṣatilẹyin fun un.

Ojusu ni, “Ti n ba ti Oṣinbajo lẹyin, o lẹtọọ bẹẹ… Mo ri bo ṣe n ṣiṣẹ, tọsan toru, olufọkansin ni, ki i ja fun apo ara rẹ nikan, o n ṣe ti awọn eeyan, o n ṣe fun ilẹ Naijiria, o si tun kawe doju ami.

‘‘Ko si ibi ti ko ti le duro ni gbogbo agbaye, at’agba at’ewe lo rọ ọ lọrun, oiha daadaa lo kọ si awọn ohun tuntun nipa imọ ẹrọ tuntun to n jade bayii, o si maa n wa ọna abayọ si iṣoro gbogbo. Ko na mi ni kọbọ lati ni ibaṣepọ pẹlu iru ẹni bẹẹ.

“Ohun ti mo n wa nile aye? Mo n wa awujọ to dara, awujọ ti mutumuwa yoo ti mọ’ru eniyan ti wọn n ṣe. Mo n wa awujọ, nibi ti awọn kan o ti ni i maa ko gbogbo ọrọ ilu jọ sinu apo wọn.

“Fun idi eyi, ti n ba ri ẹni to ni gbogbo awọn iwa daadaa yii, mo ni ẹtọ lati ṣe atilẹyin fun iru ẹni bẹẹ. Ti Ọṣinbajo ba sọ lọla pe oun yoo dupo aarẹ, n o ni awijare kankan ju ki n ti i lẹyin. Ma a si ṣiṣẹ fun un.

‘‘A ṣi n reti Ọṣinbajo lati jade waa sọ fun wa boya oun naa yoo dupo aarẹ tabi bẹẹ kọ. Yoo wu emi gẹgẹ bii ẹnikan pe ko ṣe bẹẹ, ṣugbọn ko ti i jade, fun idi eyi, a oo duro, akoko si kuku wa.’’ Ojudu lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply