Yoo to ọdun mẹẹẹdọgbọn sasiko yii ki ẹya Igbo too di aarẹ Naijiria – Joe Igbokwe

Faith Adebọla

 Ilu-mọ-ọn-ka ọmọ bibi ẹya Ibo kan, to tun jẹ ọkan lara awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Oloye Joe Igbokwe, ti sọ pe pẹlu b’oun ṣe wo ṣaakun eto oṣelu orileede wa lasiko yii, ati ihuwasi awọn eeyan ẹya oun, o kere tan, yoo ṣi gba to ogun ọdun si ọdun mẹẹẹdọgbọn pẹlu iṣẹ aṣekara ki ẹnikẹni lati apa ilẹ Igbo too le dori aleefa iṣakoso orileede Naijiria gẹgẹ bii aarẹ.

Igbokwe sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an yii, lasiko to n fesi lori bawọn kan ṣe bẹnu atẹ lu ọrọ to ti kọkọ gbe sori ẹrọ ayelujara, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii. Ninu ọrọ naa lo ti sọ pe awọn eeyan ẹya Igbo n ṣe bii onworan lagbo oṣelu, dipo ki wọn jẹ olukopa.

Igbokwe ni: “Iṣoro ta a ni niyẹn. Ẹyin eeyan ti ẹtanu ti jaraaba aye ẹ yii maa n ro pe ẹyin ni ẹ daa ju gbogbo eeyan yooku t’Ọlọrun da saye lọ, iyẹn si niṣoro ti ẹya Igbo ni loni-in.

Jisienu Ike. Ọdọọdun ti eto idibo ba waye la maa n kawọ mọri. Ẹ kopa ninu oṣelu. Mbanu, ẹ ni rara. Ẹ ṣọrẹ pẹlu awọn eeyan yikayika Naijiria, Mbanu, ẹ lẹ o ṣe. Ẹ ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn ẹya ati iran mi-in, Mbanu, ẹ ni bẹẹ kọ. A ti sọ ara wa di onworan ni Naijiria. Ẹ jẹ ki n sọ ootọ fun yin, wọn ti pari ọrọ lori eto idibo ọdun 2031, koda ti ọdun 2039 paapaa ti lọ. Ẹ mura si i.

“Ṣugbọn ẹ lọọ mọ lọkan yin , kẹ ẹ si fẹdọ leri oronro pe o maa to ogun ọdun si ọdun mẹẹẹdọgbọn pẹlu iṣẹ aṣelaagun ati aayan gidi ki ọmọ Ibo kan too depo aarẹ orileede Naijiria yii. Ojoojumọ ni ọrọ ilọsiwaju wa n polukurumuṣu si i, o si n dun mi wọra.”

Ni ti abajade esi idibo tọdun yii to re kọja, alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko tẹlẹ ọhun sọ pe bi ẹnikẹni ba fi le gbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) lo jawe olubori, pe boya wọn dọgbọn si i ni, a jẹ pe ko si irọ kan ti onitọhun ko le gbagbọ mọ laye rẹ niyẹn.

Leave a Reply