Yoruba Wikipedia bẹrẹ ajọṣepọ pẹlu Yoruba World Centre 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati le ṣe itan, ede ati aṣa Yoruba lọjọ, ajọ orisun imọ agbaye nni, Wikipedia, ti ṣetan lati ṣe ajọṣepọ pẹlu Yoruba World Centre, iyẹn ajọ Yoruba Agbaye.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹgun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, lawọn alakooso Yoruba Wikipedia, eyi ti Aarẹ Mikaeel Sodiq ati Isaac Ọlatunde ko sodi, fi iwe adehun ajumọṣepọ ọhun le awọn oludari Yoruba World Centre lọwọ lasiko abẹwo ti wọn ṣe si ọfiisi ajọ Yoruba Agbaye ninu ọgba Fasiti Ibadan (University of Ibadan, UI).

Oludasilẹ ajọ Yoruba Agbaye, Alao Adedayọ,

pẹlu Arabinrin Labakẹ Owolabi ti i ṣe alaamojuto ajọ naa, atawọn eeyan pataki bii Baalẹ Oluyọle nilẹ Ibadan, Yẹmi Ogunyẹmi; Ọjọgbọn Akin Alao, olukọ ẹka imọ nipa itan ni Fasiti Ifẹ, Ile-Ifẹ; Alagba Tunde Kelani, to tun jẹ alakooso ileeṣẹ Opomulero (Mainframe), to n gbe ere agbelewo Yoruba jade, ni wọn gbalejo awọn aṣoju ajọ to ba wọn lalejo naa.

Afojusun ajọ mejeeji pẹlu ajumọṣepọ yii ni lati gbe awọn iwe Yoruba sori itakun agbaye lọna ti awọn oluwadii ati gbogbo eeyan kaakiri agbaye yoo fi le maa lo awọn iwe naa gẹgẹ bii aritọkasi ninu iwe tabi iṣẹ iwadii wọn.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Ọlatunde ti i ṣe ọkan ninu awọn oludasilẹ Yoruba Wikipedia lorileede yii ṣe sọ, “Iṣoro ta a ni pe ni gbogbo igba ta a ba ti gbe imọ Yoruba kan sori Wikipedia, awọn eeyan ki i ni igbagbọ ninu ẹ nitori a ki i lanfaani lati sọ pe inu iwe bayii bayii la ti ri kinni yii, ẹni bayii bayii lo kọ ọ. Ṣugbọn pẹlu ọpọlọpọ iwe to wa lọfiisi ajọ Yoruba World Centre yii, yoo le rọrun fun wa lati tọka si orukọ iwe ta a ti mu imọ jade pẹlu orukọ ẹni to kọ ọ.

“Lara afojusun wa pẹlu ajumọṣepọ yii ni lati gbe ajọ Yoruba World Centre larugẹ laarin awọn akẹkọọ atawọn oluwadii kaakiri agbaye.

Ninu ọrọ tiẹ, Oludasilẹ ajọ Yoruba World Centre, Alagba Alao Adedayọ, to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ iweeroyin ALAROYE, sọ pe “Inu wa dun lati ba Yoruba Wikipedia ṣe pọ, lara awọn nnkan ta a ti n wa naa ree, nitori afojusun wa ni lati gbe aṣa, itan ati iran Yoruba goke agba.

“Lati ọdun 2014 ni mo ti n fi owo ara mi ra iwe sibi. Ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe ilu oyinbo ni mo ti ra ọpọ ninu awọn iwe Yoruba to wa nibi. Nibi ti oriṣiiriṣii iwe ta a ni nibi si pọ de, teeyan ba fẹẹ ṣe iwadii lati gboye ọmọwe nipa Yoruba, o le ri gbogbo iwe to nilo nibi.

“Awa ni nnkan ti ẹ n wa, ẹyin ni irinṣẹ tẹẹ fẹẹ lo, ta a ba pa mejeeji pọ, gbogbo aye lo maa ṣanfaani fun. A fẹ ki Wikipedia lo imọ ẹrọ tiwọn lati mu ilọsiwaju ba wa, awọn (Wikipedia) ni imọ ẹrọ, awa (Yoruba World Centre) ni imọ ibilẹ”.

“A ni ajọṣepọ pẹlu awọn ajọ bii Centre for Yoruba Language Engineering (CEYOLENG); Ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa, the Yoruba Studies Association (YSAN) the DAWN Commission ati bẹẹ bẹẹ lọ. Akitiyan awọn lajọlajọ atawọn lẹgbẹlẹgbẹ wọnyi yoo mu ki afojusun ti Yoruba Wikipedia ni pẹlu ajumọṣepọ wa yii tete kẹsẹ jari.

Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo ṣi ajọ International Centre for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC) ninu ọgba Fasiti Ibadan (University of Ibadan) lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021. INCEYAC ọjọ naa lo pada di iya to bi ọmọ tuntun ta a mọ si Yoruba World Centre saye lonii.

Leave a Reply