Yoruba World Centre fẹẹ ṣeto nla fun Olubadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo eto lo ti to bayii lori eto nla ti awọn Yoruba World Centre, iyẹn ajọ Yoruba Agbaye fẹẹ ṣe fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba (Ọmọwe) Mohood Ọlalekan Iṣọla Balogun.

Eto pataki ọhun, eyi ti yoo waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, ni wọn fẹẹ ṣe lati ṣami ọgọrun-un (100) ọjọ ti Ọba Balogun gori itẹ awọn baba nla ẹ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, nigbimọ ọhun ṣabẹwo si ori ade naa laafin ẹ to wa lagbegbe Alarere, n’Ibadan. Olugbekalẹ ajọ Yoruba World Centre, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to tun jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE lo ko igbimọ naa sodi.
Lara awọn ọmọ igbimọ ọhun to kọwọọrin pẹlu alakooso ajọ naa ni Baalẹ Oluyọle nigboro ilu Ibadan, Baalẹ Yẹmi Ogunyẹmi, Ọjọgbọn Sọji Adejumọ, Alagba Tunde Kelani ati Arabinrin Labakẹ Owolabi ti i ṣe akọwe agba igbimọ ọhun.
Nigba to n ṣalaye pataki ayẹyẹ naa, Ọgbẹni Adedayọ sọ pe “a waa ki yin ku oriire fun ti ori itẹ awọn baba nla yin tẹ ẹ gun laipẹ yii. A waa fẹẹ sọ fun yin pe awa Yoruba World Centre naa maa ṣe ayẹyẹ tiwa fun yin yatọ si eyi ti gbogbo Ibadan ti ṣe

“A fẹẹ ṣe e lọna to jẹ pe gbogbo agbaye lo maa fẹran rẹ. Ta a ba lu ilu gangan, ta a lu ṣẹkẹrẹ, ta a kọrin etiyẹri, awọn eeyan ko ni i ri i bii nnkan awọn ara oko, nitori a fẹẹ ṣe e nilana agbaye ni, awọn olowo atawọn ọlọla to ba si ri i yoo le fẹẹ nawo si i lati mu idagbasoke ba a. Awa naa yoo si jẹ ki wọn mọ pe ki i ṣe pe a deede ṣe e, Olubadan laṣe e fun.
Nigba n sọ nipa ajọ naa fun Ọba Balogun, Ọga awọn Alaroye ṣalaye pe “lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, la da ajọ kan ta a pe ni International Center for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC) silẹ, Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lo waa ṣi i ninu ọgba Fasiti Ibadan (UI).

INCEYAC ọhun lo bi Yoruba World Centre yii. Idi ta a ṣe da a silẹ ni pe kaakiri agbaye, teeyan ba fẹẹ ṣewadii, boya iwadii lori itan ni o, boya iwadii lori aṣa Yoruba ni o, tabi iwadii yoowu ti eeyan ba fẹẹ ṣe, iru ẹni bẹẹ ko ni i jokoo si oju kan, yoo maa kaakiri lati yunifasiti kan si omi-in ni. Nitori pe o n lọ kaakiri yii ko ni i jẹ ko ri ojulowo iṣẹ to fẹẹ ṣe ṣe kiakia laṣeyọri.
“Nitori ẹ la ṣe wo o pe o yẹ ka ni ibudo kan to maa jẹ gbogbo nnkan Yoruba ti eeyan ba fẹ, yala nipa awa Yoruba ta a wa nile ni o, atawọn to wa ni Brazil ni o, atawọn to wa nilẹ olominira Benin, ibi yoowu ti Yoruba ba wa, ka ni ibudo ta a ti le ba awọn nnkan wa, nibi ta a ti le maa ri awọn ohun eelo ti awọn oluwadi yoo ti maa ri ohun eelo iwadii wọn. Bi apẹẹrẹ, teeyan ba nilo ohunkohun nipa Olubadan tabi ọba ilẹ Yoruba mi-in, aaye maa wa ti oluwarẹ yoo lọọ yẹwo, to si maa ba gbogbo ohun to n fẹ nibẹ. Awọn orin wa, awọn nnkan aṣa wa, a ni lati ṣe wọn lọjọ.
Ko si iran ti ko ni aṣa. A fẹẹ ta aṣa wa ji pada. Ọpọlọpọ iran ti ko ni itan ati aṣa to Yoruba, wọn ti n lo aṣa wọn fun agbega orileede wọn. Iran ti ko ba ni itan, o ti parẹ ni. Yoruba si ni aṣa ati itan to pọ.”
Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, waa fi idunnu ẹ han si eto naa, bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin rẹ fun ajọ Yoruba Agbaye lori ohun gbogbo ti wọn ba fẹẹ ṣe.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “inu mi dun si aṣa ati iṣe Yoruba tẹ ẹ mu lọkun-un-ku dun. Mo ri i pe gbogbo ẹyin tẹ ẹ wa ninu Yoruba World Centre yii lẹ jẹ olugbega aṣa Yoruba.”

Leave a Reply