Monisọla Saka
Adura tawọn eeyan maa n ṣe ni pe ka ma gba ibi ta a gba wa saye lọ sọrun, ṣugbọn adura yii ko ṣẹ mọ ọkunrin kan to n jẹ Utobong lara, pẹlu bo ṣe dagbere faye lẹyin to lo oogun ale tan.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni oniroyin kan to fipinlẹ Rivers ṣebugbe, Allwell Ene, gbe ọrọ naa sori ẹrọ ayelujara.
Alaye to ṣe sibẹ ni pe ile itura kan to wa ni Osina Street, Mile 2, Díòbú, Port Harcourt, nipinlẹ Rivers, ni wọn ti ba oku gende-kunrin ọhun.
Ohun ti wọn lo ṣẹlẹ ni pe ọkunrin yii gbe obinrin wa si otẹẹli ti wọn ko darukọ rẹ ọhun ni. Lasiko ti wọn n ṣe yunkẹ yunkẹ lo jọ pe ọkunrin naa gbabẹ sọda sodikeji, nitori oogun ale to lo ko too ba obinrin naa sun.
O ni, “Gbalanja ni wọn ba oku ọkunrin naa ninu yara ti iṣẹlẹ buburu naa ti waye. Bo tilẹ jẹ pe obinrin to gbe lọ si otẹẹli ọhun ti fẹsẹ fẹ ẹ Oogun oloro Tramadol paali meji, ohun mimu afunnilagbara Bullet alawọ dudu meji, ati oriṣiiriṣii oogun tawọn ọkunrin n lo fun ibalopọ ni wọn ba lẹgbẹẹ oku rẹ”.
Awọn ti wọn mọ oloogbe sọ pe iṣẹ gẹrigẹri (Barber), lo n ṣe, wọn ko si ti i mọ ohun to ṣeku pa a, boya latari aṣilo oogun ni tabi ko jẹ pe ẹni-aimọ kan lo pa a.