Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ohun ti ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan mọ ọn jẹ ti gbe e dele -ẹjọ bayii o, iyẹn Yusuf Kọrọde to n gbe l’Ọta, ẹni to fun ọrẹbinrin ẹ loyun, ti ko si pese ohun ti ọmọbinrin naa nilo nipo iloyun to wa.
Ọjọruu to kọja yii ni wọn wọ Yusuf to n gbe l’Ojule kẹfa, Opopona Kajọla Oluwa, l’Ọta, nipinlẹ Ogun, wa si kootu naa, ẹsun kan ṣoṣo ti wọn si fi kan an ni fifi ẹmi eeyan wewu.
Agbefọba E.O Adaraloye ṣalaye fun kootu pe oṣu kẹta, ọdun 2021, ni Yusuf ti fun ọrẹbinrin ẹ yii loyun, kaka ko si ṣetan lati di baba ọmọ, ko maa tọju ẹni to ba sun to doyun, o ni niṣe lo pa ọmọbinrin naa ti, ti ko fun un lowo ti yoo fi maa ṣetọju ara ẹ ati oyun to wa ninu ẹ. Agbefọba ni iwa ọdaran ni eyi, o lodi sofin ni abala ọọdunrun le mọkandinlogoji ni ( 339).
Yusuf ti wọn fẹsun kan naa sọrọ, o loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Eyi lo jẹ ki Adajọ A.O Adeyẹmi faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira (100,000) pẹlu oniduuro meji niye kan naa.
Adajọ paṣẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu, wọn gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ, wọn si gbọdọ le ṣafihan owo-ori sisan wọn funjọba ipinlẹ Ogun.