Zainab pariwo n’Ibadan: Alhaji ti fẹẹ fi ibalopọ ba temi jẹ, ẹ tu wa ka

Ọlawale Ajao, Ibadan

Obinrin oniṣowo kan, Alhaja Zainab Mabinuori, ti rọ kootu ibilẹ Ile-Tuntun to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lati fopin si ibaṣepọ ọlọdun mọkanla to wa laarin oun atọkọ ẹ, Alhaji Nurudeen Mabionuori. O lọkunrin naa ti fẹẹ fi ibalopọ baye oun jẹ.

Iya to fi adugbo Muslim-Odinjo, n’Ibadan, ṣebugbe yii ṣalaye pe gbogbo igba ti oun atọkọ oun ba ti jọ laṣepọ laisan maa n ṣe oun, idi si niyẹn ti oun ko ṣe gba fun un mọ, ko ma fi ibalopọ ba toun jẹ.

“Ninu oṣu kẹta, ọdun 2014, emi atiwọn ni ibalopọ gẹgẹ bii tọkọ-tiyawo, ba a ṣe pari ẹ tan ni gbogbo agọ ara mi daru patapata, ti mi o si gbadun ara mi mọ”, bẹẹ lobinrin oniṣowo naa sọ.

O tẹsiwaju pe “Mo ni Alaaji, ki lo de, latigba ta a ti laṣepọ ni mi o ti gbadun ara mi mọ, ki lo ṣẹlẹ. Wọn ni eéwo kan lo mu awọn nibi nnkan ọmọkunrin, mo ni ẹ yaa tọju ara yin o.

“Awọn ko le ṣe ki wọn ma ba obinrin laṣepọ ni tiwọn, mo ni ki wọn yaa maa ri i pe wọn n lo rọ́bà idaabobo nigbakuugba ti wọn ba ti fẹẹ sun mọ mi. Ṣugbọn bi wọn ṣe n lo o to naa, gbogbo igba ta a ba jọ laṣepọ laisan maa n ṣe mi. Idi niyẹn ti mi o ṣe gba fun wọn lati sun mọ mi mọ.”

Alhaji Nurudeen lo pẹjọ lati kọ iyawo ẹ silẹ, ṣaaju lo si ti ṣapejuwe Zainab gẹgẹ bii oniwahala obinrin.

Ọkunrin oniṣẹ ọwọ yii fi kun un pe “Lọsẹ to kọja, nitori pe mi o ti i fun un lowo ounjẹ, o (Zainab) fa aṣọ ya mọ mi lọrun, o mu kọkọrọ mọto mi ati bata mi, o loun ko ni i jẹ ki n jade lọ sibi iṣẹ, afi ti mo ba too fun oun lowo.

“Gbogbo ẹbi lo ti da si ọrọ ija wa, sibẹ, iyawo mi ki i yee fa ijangbọn. Ko jẹ ki gbogbo akitiyan ẹbi awa mejeeji lati ri i pe alaafia jọba laarin wa seso rere.”

Olori igbimọ awọn adajọ kootu naa, Oloye Henry Agbaje ti sun igbẹjọ naa si Ọjọruu, ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii, iyẹn Wẹsidee ọsẹ to n bọ yii, nigba to gba awọn tọkọ-tiyawo naa niyanju lati ma ṣe ba ara wọn ja tabi fa wahala ko too di ọjọ naa.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: