Zakaraya rẹwọn he, bibeli ati ohun mimu awọn ọmọde lo lọọ ji ni ṣọọṣi

Monisọla Saka

Nitori aini amojukuro ati afọwọra to ṣe, l’Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, nile-ẹjọ Grade 1, Area Court, to wa lagbegbe Kabusa, niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa, ran ọkunrin kunlekunle ẹni ọdun ọgbọn ọdun (30), kan, Zakaraya Usman lẹwọn oṣu meji.
Ẹsun ole jija ni wọn fi kan an. ALAROYE lẹyin to ji Bibeli mẹrin, ohun mimu ẹlẹrindodo tawọn ọmọde fẹran lati maa mu, Caprisonne, atawọn nnkan mi-in to jẹ tawọn ọmọ ijọ.
Lara awọn nnkan ti wọn lọkunrin to rin kọsẹkọsẹ wọnu ile ijọsin Winners Chapel yii ji ni Bibeli kekere mẹta, Bibeli nla kan, Caprisonne mẹrinla, omi mimu onike meji, iwe-ẹri mejidinlogun to jẹ tawọn ọmọ ijọ, ati fọọmu mẹrinlelọgọfa to tun jẹ tawọn ọmọ ijọ naa. Bakan naa ni wọn tun lo ji aṣọ pelebe tawọn ọdẹ aṣọgba n wọ lori aṣọ wọn, ẹwu meji, aṣọ awọleke meji, aṣọ inuju (handkerchief) meji, baagi meji ati ọpọlọpọ owo.
Ọlọpaa agbefọba ni kootu ọhun, Ọgbẹni O. S. Ọshọ, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe Ọgbẹni David Usman, ti i ṣe olori awọn ọdẹ to n ṣọ ile ijọsin Living Faith Church(Winner’s Chapel), ẹka rẹ to wa lagbegbe Durumi, lo waa fọrọ naa to awọn leti.
O ṣalaye siwaju si i pe gbogbo awọn nnkan tọkunrin naa fọwọ kọ ni ṣọọṣi yii lawọn ọlọpaa ti ri gba lọwọ ẹ lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo.
Nigba ti wọn bi afurasi ọdaran naa boya o jẹbi tabi ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o ni loootọ loun jẹbi awọn ẹsun naa,  ṣugbọn ki Onidaajọ Abubakar Sadiq ṣaanu oun.
Lẹyin naa ni adajọ fun un lanfaani lati san ẹgbẹrun mẹwaa Naira, (10,000), tabi ko ṣẹwọn oṣu meji. Bakan naa ni adajọ tun gba ọkunrin kunlekunle ọhun nimọran lati ma ṣe ṣan iru aṣọ bẹẹ ṣorò mọ, nitori ko ni i le janfaani oore-ọfẹ ti ile-ẹjọ fun un yii mọ nigba mi-in.

Leave a Reply