Monisọla Saka
Ọkunrin kan to n ṣiṣẹ awakọ, ti pade iku ẹ lẹsẹ o gbeji, nigba tawọn agbebọn yinbọn pa a labule Essanti, nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ Kwara, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Gẹgẹ bi awọn agbebọn atawọn ajinigbe ṣe n ṣoro lagbegbe Ijọba ibilẹ Patigi, Kaiama atawọn agbegbe mi-in nipinlẹ Kwara lọwọ yii, jinnijinni ti bolẹ, awọn eeyan agbegbe naa si ti tun ko sinu ipaya, pẹlu ọkunrin ti wọn ko darukọ ẹ ti wọn tun gbẹmi ẹ lojiji yii.
Ọkan ninu awọn araalu naa to sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe lasiko ti ọkunrin naa n dari bọ lati Patigi, nibi to ti lọọ ja awọn ero silẹ, lo ti kagbako awọn olubi ẹda naa. O ni ṣadeede ni mọto ọkunrin naa daṣẹ silẹ nigba to de Essanti, amọ nigba to ṣe e titi ti ọkọ ọhun ko ṣiṣẹ, ti aago mọkanla alẹ si ti lu ba a nidii ẹ lo pọkan pọ pe oun yoo kuku sun sinu mọto ọhun mọju.
Nibẹ ni akọroyin wa gbọ pe awọn agbebọ yii ka a mọ, ti wọn si yinbọn pa a. Wọn ni ko sẹni to mọ idi ti wọn fi pa ọkunrin naa ati bi wọn ṣe pa a. Ṣugbọn ọrọ naa ko ṣajoji sawọn eeyan agbegbe Ariwa Kwara yii, nitori bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe nibẹ, ni wọn n wọlu lọọ pa wọn lai ṣẹ lai ro.











Leave a Reply