Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Sokoto tẹlẹ, toun naa dupo Aarẹ to kọja lẹgbẹ oṣelu PDP ṣaaju ibo abẹle ẹgbẹ wọn, Aminu Tambuwal, ti fẹsun kan Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati ẹgbẹ oṣelu to wa nipo bayii, All Progressives Congress (APC), pe awọn ni wọn n fọpomọyọ lawọn ẹgbẹ oṣelu alatako, ti wọn n da a ru, ti wọn ko si fẹ ki o toro niṣẹẹju kan.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni ọkunrin olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ yii sọrọ naa. O ni Tinubu ati ẹgbẹ APC ti mọ-ọn-mọ dẹ pakute nla kalẹ fun awọn ẹgbẹ alatako orilẹ-ede yii lati da a wo, ki wọn run jegejege, lai ṣee ṣa jọ mọ.
Gomina Sokoto tẹlẹ to ti n ba ẹgbẹ oṣelu alaṣepọ, African Democratic Congress (ADC) ṣe bayii ni, “Tẹ ẹ ba wo nnkan to n ṣẹlẹ lawọn oriṣiiriṣii ẹgbẹ alatako to wa ni Naijiria lonii, wọn o nilo lati sọ fun yin, ko si bi wọn ṣe le se tabi ki wọn kọ jalẹ to, titi kan Aarẹ Bọla Tinubu funra ẹ, pe awọn ko lọwọ ninu bi wọn ṣe n da ẹgbẹ alatako ru, ati lati ba akitiyan wọn jẹ, ko ri bẹẹ, irọ ni.
“Mi o fẹsun kan wọn o. Mo n sọ ọ lai dọwọ bo ẹnu ni pe awọn ni wọn wa nidii bi wọn ṣe maa da gbogbo ẹgbẹ to jẹ alatako fun wọn ru”.
Nigba ti wọn bi i leere boya o ni ẹri lati fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, Tambuwal to duro lori ọrọ ẹ ni, “Mo n sọ ọ bo ṣe jẹ ni, ki i ṣe pe mo n fura si wọn. Awọn gangan ni wọn n pa gbogbo idan buruku yii”.
Ẹ oo ranti pe latigba ti kurukẹrẹ ipalẹmọ eto idibo ọdun 2027 ti n lọ, ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ alatako bii PDP, Labour Party atawọn ẹgbẹ mi-in ti n rọ lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣugbọn nitori wahala ti wọn ni Tinubu n da silẹ ninu ẹgbẹ awọn, ati ogun abẹle to n lọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu yii, ti ko jẹ ki wọn roju raaye jokoo lori ọna abayọ ati bi wọn ṣe maa rọwọ mu lasiko ibo to n bọ, lo mu kawọn ọmọ ẹgbẹ wọn maa pọ soke raja lọ sinu ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ.
Omi alaafia awọn ẹgbẹ yii ti ko figba kan toro naa ni Tambuwal sọ ni gbangba pe iṣẹ ọwọ Aarẹ Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu rẹ ni.
Nitori ati le rẹyin ijọba Tinubu yii, ti wọn yoo si gba ijọba lọwọ ẹ naa ni awọn oloṣelu tinu n bi lati awọn ẹgbẹ alatako ṣe kora wọn jọ sinu ẹgbẹ ADC, ti wọn fẹẹ fi ṣaṣepọ lati le Tinubu danu nipo.
Awọn bii Atiku, Obi, Rauf Arẹgbẹṣọla, ti i ṣe gomina Ọṣun tẹlẹ, Rotimi Amaechi, David Mark, Tambuwal funra ẹ atawọn jankanjankan mi-in ti ni awọn yoo jẹwọ fun Tinubu lọdun 2027 pe awọn ki i ṣe ọkọ oju omi to n ri wọlẹ lọ to fi n ṣapejuwe ẹgbẹ awọn, nitori awọn maa jọ wọn loju lọjọ ibo.











Leave a Reply