alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ara Peter Obi ko ya o, eyi lohun to ṣẹlẹ si i

Adewale adeoye

‘O wu mi ki n maa ṣe bi mo ṣe n ṣe tẹle lọ, ki n maa lọ soke-sodo, ki n maa ba ẹbi, ara ati ojulumọ gbogbo ṣe, ṣugbọn awọn dokita ti wọn n ṣetọju mi ti gba mi nimọran pe ki n fun ara mi ni isinmi ọlọjọ ranpẹ kan na. Wọn ni ara ki i ṣe okuta, mo nilo isinmi diẹ. Fun idi eyi, o ṣee ṣe ki n ma le yọju sawọn eto kọọkan ti wọn ba fiwe pe mi si lọsẹ yii nilẹ yii ati l’Oke-Okun, mo fẹẹ sinmi diẹ.’ Eyi lọrọ to n jade lẹnu ondije dupo aarẹ orileede yii lasiko ibo ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu LabourPeter Obi.

Ọjọ Abamẹta Satidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii ni Peter Obi sọrọ ọhun di mimọ lori ẹrọ ayelujara rẹ kan pe oun maa fun ara oun nisinmi ọlọjọ diẹ nitori awọn dokita ti wọn n ṣetọju oun ti gba oun nimọran lati ṣe bẹẹ.

Atẹjade kan to fi sita lo ti ṣalaye pe Aipẹ yii ni mo lọ si ode kan niluu Enugu, lẹyin ti mo pari nibẹ ni mo lọ sileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Good Hope Specialist Hospital, to wa lagbegbe Isulo, nijọba ibilẹ Orumba, nipinlẹ Anambra. Awọn ijọ kan ni wọn fiwe pe mi sibi eto ikowojọ kan, bẹẹ ni mo fun wọn ni miliọnu mẹwaa Naira gẹgẹ bii iṣe mi nigba gbogbo.

Lati ibẹ ni mo ti lọ siluu Owerri fun ayẹyẹ mi-in, eyi ti Barista Nnaemeka Maduagwu, pe mi si, o fẹẹ da gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Alhaji El Rufai, ti i ṣe ọga rẹ tẹlẹ lọla ni. Nibi eto naa ni ara mi ko ti ya, lojuẹsẹ ni mo lọọ ṣe ayẹwo nileewosan kan to wa lagbegbe naa. Ibẹ ni dokita to ṣe ayẹwo fun mi ti gba mi nimọran pe ki n fun ara mi nisinmi ọlọjọ diẹ’’.

Fun idi eyi, Obi loun maa gbọrọ si dokita oun lẹnu, toun si maa fun ara oun nisinmi diẹ.

O waa tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu, paapaa ju lọ, awọn ololufẹ rẹ gbogbo to yẹ ko wa lọdọ wọn laarin ọsẹ yii, ṣugbọn ti ko ni le wa pẹlu wọn pe ki wọn ṣe aforiji foun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *