Monisọla Saka
Kayeefi lọrọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun tẹnikẹni ko ti i mọ inu ẹgbẹ ti wọn ti wa, ti wọn lọọ paayan mẹrin sibi ti wọn ti n sinku ọdọmọkunrin kan.
Kiakia ni owe oku n sunkun oku, akaṣọleri n sunkun ara wọn ṣiṣẹ nibi eto isinku naa, nitori ọpọ awọn to lọ ni ko pada sile laaye.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, ti wọn fọrọ naa lede sọ pe awọn ti n wa awọn olubi ẹda ti wọn pa awọn oludaro, nibi eto isinku ọkunrin ọmọ ọdun mejidinlogun kan, labule Ezi, Ogidi, nijọba ibilẹ Ariwa Idemili, nipinlẹ naa.
Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni awọn agbebọn ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ya lọ sibi ti wọn ti n ṣeto isinku naa, ko si din ni eeyan mẹrin ti wọn pa loju–ẹsẹ, n ni oku di pupọ nilẹ, tawọn bii mẹẹẹdogun si fara pa gidi gan-an.
Wọn ni awọn mọlẹbi oku, ara, ọrẹ ati ojulumọ ni wọn pe jọ lalẹ ọjọ naa lati ṣẹyẹ ikẹyin f’ọmọ to ku, lasiko naa lawọn jagunlabi ya lu wọn lojiji, ti wọn da ibọn bo awọn eeyan naa.
Bo tilẹ jẹ pe mẹrin lawọn ọlọpaa sọ pe awọn olubi ẹda naa pa, awọn tọrọ ṣoju wọn sọ pe iye eeyan ti wọn pa nibẹ ju mẹrin lọ.
Ẹni kan to forukọ bo ara ẹ laṣiiri sọ pe, “Lojiji lawọn ọdaju ẹda naa ya de lọjọ Tọsidee yẹn, ti wọn ṣina ibọn bolẹ fawọn to peju sibi eto isinku yii.
“Ni ayika ile oloogbe lawọn ẹbi atawọn ara ti n ṣọfọ lọwọ nigba tawọn agbebọn ọhun de, ti wọn n yinbọn sawọn to waa ba wọn ṣedaro, tawọn eeyan ọhun si n sa kabakaba, ti onikaluku n sa asala fun ẹmi wọn.
Ọkada ni wọn gun wa, bi wọn si ṣe pari iṣẹ ibi ti wọn ba wa ni wọn ti parẹ bii iso”.
Ẹnikan toun naa mọ nipa iṣẹlẹ yii ṣalaye pe, “Awọn ọrẹ oloogbe pejọ lati fi aisun ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un ni. Wọn ti gbagbera bi wọn ṣe n fi ọti ṣe faaji, tawọn mi-in n fa sìgá ati oriṣiiriṣii nnkan mi-in. Laarin asiko ọhun lawọn ta a n wi yii de, ti wọn da ibọn bo awọn to jokoo jẹẹjẹ wọn yii.
“Nnkan to n fu awọn araalu lara bayii ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako fun ẹgbẹ mi-in ni wọn jade waa gbẹsan. Eeyan to le ni mẹjọ ni wọn pa, tawọn mi-in si gbọgbẹ latara ọta ibọn to ba wọn.
“Wọn ti gbe oku awọn eeyan ti wọn pa lọ si mọṣuari, awọn to fara pa naa n gba itọju lọwọ nileewosan”.
Ṣugbọn ninu atẹjade ti Tochukwu Ikenga, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Anambra fi sita, o ni eeyan mẹrin lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe iwadii awọn fi han pe iṣẹlẹ naa ni i ṣe pẹlu ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa Anambra ti bẹrẹ iwadii to jinlẹ lori iṣẹlẹ naa, gbogbo akitiyan lawọn si n ṣe lati wa awọn ọbayejẹ naa kan, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.











Leave a Reply