alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ibo ọdun 2023: Aṣiṣe nla la ṣe bi ẹgbẹ PDP ṣe fun Atiku ni tikẹẹti

Adewale Adeoye

Ọkan lara awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Sẹnet Abba Moro, to tun jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ PDP, ti ni aṣiṣe nla gbaa ni bi ẹgbẹ PDP ṣe fa igbakeji aarẹ orileede yii tẹlẹ, Alhaji Atiku Abubakar, silẹ lati dije dupo aarẹ lọdun 2023.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni Abba Moro sọrọ ọhun di mimọ nibi eto ori tẹlifiṣan Channels l’Abuja. O ni aṣiṣe nla gbaa ni bi ẹgbẹ PDP ṣe ti j ki Alhaji Atiku Abubakar to jẹ ẹya Hausa tun gba tikẹẹti ẹgbẹ ọhun lati dije dupo lọdun 2023, niwọn igba to jẹ pe Oloogbe Buhari to ṣẹṣẹ pari ijọba tan, ẹya Hausa ni.

Ọkunrin yii ni, ‘Ko sohun meji to da ẹgbẹ PDP ru ju bi a ṣe fa Alhaji Atiku Abubakar kalẹ lorukọ ẹgbẹ wa lọ. Lasiko ibo ọdun 2023 yẹn, a n wa oloṣelu to lorukọ daadaa laarin ilu to le koju ẹni yoowu ti APC ba fa kalẹ ni, ṣugbọn aṣiṣe nla gbaa lo jẹ fun wa, nitori ṣe lawọn araalu kọyin si igbesẹ wa ọhun. Ohun to si fa a ko ju pe ọpọ ni wọn n sọ pe Oloogbe Buhari to ṣẹṣẹ gbe ijọba silẹ, ẹya Hausa ni. Wọn gbagbọ pe ko yẹ ko tun jẹ ẹya Hausa lo maa tun pada sile ijọba orileede yii. Wọn fajuro gidi si igbesẹ wa ọhun, bẹẹ la padanu aimọye nnkan, ẹgbẹ PDP daru tan, diẹ lo ku. Ọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn kuro, ti wọn lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in. Ṣugbọn a ti kọ ẹkọ nla bayii, iru nnkan bẹẹ yẹn ko tun le ṣẹlẹ si wa mọ lae’’.

Abba Moro ni nitori pe awọn ti kọ ẹkọ latari ohun to ṣẹlẹ sawọn lasiko ibo ọdun 2023. awọn ti fẹnu ko pe ki ẹya Yoruba tabi Igbo jẹ ondije dupo aarẹ orileede yii lorukọ ẹgbẹ PDP lasiko ibo ọdun 2027 to n bọ lọna yii.

O ni, ‘A ti pe aro ati ọdọfin inu wa ninu ẹgbẹ PDP bayii, iru aṣiṣe nla ti a ṣe lọdun 2023 ko tun le ṣẹlẹ si wa mọ lae. Ẹya igbo tabi Yoruba la sọ pe ki wọn waa jẹ ondije dupo aarẹ orileede loruko wa fun ibo ọdun 2027. Niwọn igba to jẹ pe ẹya Hausa la fi ṣe alaga ẹgbẹ wa bayii.

Ọpọ eeyan ni wọn gbagbọ pe ẹya Yoruba tabi igbo gbọdọ ṣe ọdun mẹjọ wọn pari nipo aṣẹ la ṣe gbe igbesẹ naa. Ohun aburu, ta a si kabaamọ le lori ni pe a fa Alhaji Atiku Abubakar kalẹ lorukọ ẹgbẹ PDP. Iru rẹ ko tun le waye mọ lae.

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *