alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ijọba gboṣuba fun ileeṣẹ Dangote lori bo ṣe n sanwo ori ẹ deede funjọba Ogun

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to n gbowo ori lọwọ araalu, iyẹn ‘Ogun State Internal Revenue Service’ (OGIRS) ti gboṣuba nla fun ileeṣẹ Dangote, nitori ti wọn lo n sanwo ori ẹ deede sapo ijọba ipinlẹ naa, ati pe ileeṣẹ ẹ wa lara awọn kan gboogi to jẹ aṣaaju ninu awọn ileeṣẹ to n sanwo ori sapo ijọba deede.

Aipẹ yii ni awọn lọgaa-lọgaa ẹka ileeṣẹ yii, eyi ti Abilekọ Oluwaṣeun Ọlajube, ṣaaju ikọ naa lọọ ṣe abẹwo si ẹka ileeṣẹ Dangote ti wọn ti n ṣe iyẹfun simẹnti niluu Ibeṣe, nipinlẹ Ogun. Lasiko abẹwo ọhun ni awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun yii ti dupẹ gidigidi lọwọ ileeṣẹ Dangote, lori bi wọn ṣe n sanwo ori wọn deede sapo ijọba, wọn ni aṣaaju ninu awọn ileeṣẹ gbogbo nipinlẹ naa to n sanwo ju ni wọn.

Wọn waa fi da wọn loju pe gbogbo iranlọwọ tileeṣẹ Dangote ba nilo lati maa tẹsiwaju si i ninu iṣẹ wọn lati ọdọ ijọba ipinlẹ Ogun lawọn aa fun wọn. Bakan naa lawọn aṣoju ijọba yii rọ ileeṣẹ Dangote pe ki wọn ma ṣe rẹwẹsi ọkan lori bi wọn ṣe n ṣe deede sijọba lori owoori ti wọn n san loore-koore, paapaa ju lọ, sapo ijọba ibilẹ Yewa-North.

 

Ọlajubẹ ni, ‘Ohun idunu nla gbaa lo jẹ fun ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to n ri sọrọ owoori bi ileeṣẹ Dangote ṣe n sanwo ẹ deede sapo ijọba. Bakan naa la gboṣuba nla fun wọn pe ipa pataki ni wọn n ko nipa eto ọrọ aje orileede yii ni gbogbo ọna’.

Ayyagari Subbaraidu, ti i ṣe ọga agba nileeṣẹ simẹẹnti to wa niluu Ibeṣe yii dupẹ lọwọ awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun fun bi wọn ṣe waa ṣabẹwo sọdọ awọn, paapaa ju lọ, lasiko yii. Wọn fi da awọn aṣoju ijọba ọhun loju pe ileeṣẹ Dangote ko ni i rẹwẹsi lori owoori ti wọn n san sapo ijọba ipinlẹ naa.

Sabbaraidu ni, ‘Ileeṣẹ yii mọ pe ipa pataki ni owoori sisan n ko ninu iṣakooso ijọba. Idi ree ti a ṣe n sanwo ori wa deede funjọba ipinlẹ Ogun, ipo aṣaaju la wa ninu ohun gbogbo, ipo naa la si fẹ maa wa nigba gbogbo’’.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *