Adewale adeoye
Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Sẹnetọ Gbenga Daniel, ti fajuro gidi si iroyin ẹlẹjẹ kan tawọn kan n gbe kiri pe o ti lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin ti wọn yọ ọ ninu ẹgbẹ APC. O ni ko sohun to jọ bẹẹ rara, ojulowo ọmọ ẹgbẹ APC ṣi loun, ati pe oun ko ni i lọkan lati lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in lasiko yii rara.
Atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita lori ọrọ yii lo ti ṣalaye pe, ‘‘Ko sohun to jọ bẹẹ rara pe Sẹnetọ Gbenga Daniel ti darapọ mọ PDP, inu APC lo ṣi wa, ko sohun to n wa lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko yii.
Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni wọn le Sẹnetọ Gbenga Daniel ati Kunle Fọlarin, kuro ninu ẹgbẹ naa nitori ti wọn fi ẹsun kan awọn mejeeji pe wọn n ṣoju meji pẹlu ẹgbẹ APC, ẹka tipinlẹ Ogun.
Sẹnetọ Gbenga Daniel to n ṣoju ẹkun Ogun East, nipinlẹ naa ni Alukoro eto iroyin rẹ gba ẹnu rẹ sọrọ pe ko sohun to jọ bẹẹ pe Sẹnetọ Gbenga Daniel, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC pe ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣi ni, ti ko si ni i lọkan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko yii.












Leave a Reply