alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Awa la dina ipo minisita mọ El-Rufai lọdọ Aarẹ – Ẹgbẹ ọdọ Kaduna

Monisọla Saka

 

Ẹgbẹ ọdọ awọn eeyan apa Guusu ipinlẹ Kaduna, The Youth Wing of the Southern Kaduna People’s Union (SOKAPU), ti ni iṣẹ ọwọ awọn ni iwe ẹsun to dena gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Nasir El-Rufai, lati dipo minisita mu labẹ ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita labẹ adari apapọ wọn, Akọgun Solomon Simon, ni wọn ti ṣọ iwe ẹsun tawọn kọ ta ko El-Rufai, ni ko jẹ kawọn aṣofin gba a wọle gẹgẹ bii minisita, nigba ti Tinubu fi orukọ ẹ ranṣẹ.

 

Wọn ni ninu iwe ẹsun tawọn kọ ranṣẹ sile-igbimọ aṣofin l’Abuja, tawọn si tun fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ ijọba mi-in tọrọ kan, lawọn ti ṣalaye idi ti El-Rufai ko ṣe yẹ lẹni to n dipo ijọba mu.

Wọn ni awọn ẹsun iwa ibajẹ bii titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ, aini ibọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ, lilo ofin ileeṣẹ ijọba nilokulo, ati aṣẹ to fi gba agbara lati ṣiṣẹ bo ṣe yẹ lọwọ awọn oniroyin lasiko to wa nipo gomina, lawọn ka si i lọrun.

 

Awọn ẹgbẹ yii ni gbogbo ẹri tawọn ko jọ yii ni ko jẹ kawọn aṣofin buwọ lu orukọ ẹ, ati pe nibẹ gan-an ni ibinu ati ikanra El-Rufai ti bẹrẹ, paapaa sawọn eeyan apa Guusu Kaduna.

 

Bakan naa ni wọn sọ pe ohun ti El-Rufai n reti ni pe ki Aarẹ Tinubu yọ gbogbo awọn ẹlẹsin Kirisitẹni kaakiri orilẹ-ede yii silẹ ninu ijọba ẹ, gẹgẹ boun ṣe ṣe, to n ta ko awọn ọmọlẹyin Kirisiti ipinlẹ Kaduna, lasiko to wa nipo.

 

Wọn ni anfaani ti ko ṣee ka ni awọn eeyan agbegbe Guusu Kaduna ti jẹ lọwọ ijọba to wa nipo bayii, bii awọn iṣẹ akanṣe nla nla, titi kan ileewe giga fasiti ti wọn ti n kọ nipa imọ sayẹnsi, University of Applied Sciences, ati ileewosan nla ijọba apapọ, (Federal Medical Centre) ti wọn pese fun wọn. Wọn ni gbogbo ilọsiwaju to ba agbegbe awọn yii lo ṣokunfa idi ti El-Rufai ṣe gba ori tẹlifiṣan  kan nilẹ yii lọ, nibi ti wọn ti ṣe ifọrọwerọ fun un, to si n sọrọ ta ko awọn eeyan awọn.

 

Awọn ọdọ ẹgbẹ SOKAPU yii bu ẹnu atẹ lu awọn ọrọ buruku to n jade lẹnu El-Rufai, nigba to n ṣapejuwe awọn eeyan Guusu ipinlẹ Kaduna bii oniwahala, pe wọn fẹ maa jẹ nibi ti wọn ko ṣe si, ati pe awọn ni wọn kun ileeṣẹ ijọba, wọn ni ọrọ to le dija silẹ, to si le fa ipinya lo n tẹnu ọkunrin naa jade.

 

Awọn ẹgbẹ yii waa rọ ọ lati ko ọrọ naa jẹ, ko si tọrọ aforiji, nitori ati Musulumi ati Kirisitẹni, awọn Hausa atawọn ti wọn ki i ṣe Hausa, ni wọn jọ ni Kaduna.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *