Adewale adeoye
Ṣe lọrọ di bo o lọ o yago fun mi lọjọ Aiku, Sandee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lasiko ti wọn n ṣayẹyẹ ọdun Ẹyọ, l’Ekoo. O kere tan, eeyan mẹta lawọn agbofinro agbegbe naa sọ pe o ku sinu ija itẹjẹsilẹ kan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji, eyi ti wọn fi ayẹyẹ ọdun ẹyọ tọdun yii boju.
Ṣaaju ki wahala nla ọhun too bẹ silẹ ni gbogbo eto ti n lọ mẹlọmẹlọ, ti inu awọn araalu atawọn alejo gbogbo ti wọn waa ba wọn ṣayẹyẹ ọdun Ẹyọ naa si n dun fun ohun ti wọn n ri, ṣugbọn lojiji lawọn ọmọ ilu kan tawọn naa wa ninu ẹgbẹ okunkun bẹrẹ si i koju ija sira wọn, ti wọn si n fi ohun ija oloro le ara wọn kaakiri inu ilu. Iṣẹlẹ ọhun lo fa a tawọn araalu kan ti wọn ko fẹẹ farapa ṣe n sa asala fun ẹmi wọn.
Nigba to maa fi di Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ọrọ naa burẹkẹ si i, ti wọn si n yinbọn sira wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe ajọdun ọdun ẹyọ ti wọn maa n ṣe niluu Eko lọdọọdun ni wọn ṣe lọdun yii, eyi to bẹrẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ṣugbọn tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n kopa ninu ajọdun naa lo asiko ayẹyẹ ọdun ọhun lati koju ija sira wọn, ti wọn si pa ara wọn nipakupa.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti ṣalaye pe, ‘‘Ifọkanbalẹ ati karakata ọja ti n lọọ deede laarin ilu Eko, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn jẹ ọmọ ilu ti wọn n kopa ninu ajọdun ọdun Ẹyọ, l’Ekoo, ni wọn fẹẹ lo akoko naa lati koju ija sira wọn, wọn fẹẹ fi ọdun naa kẹwọ ni, ṣugbọn awọn agbofinro ipinlẹ Eko ti kapa iṣẹlẹ naa. Eeyan mẹta ni wọn padanu ẹmi wọn lasiko ija igboro to waye lasiko ajọdun ọdun ẹyọ tọdun yii.
Alukoro ni awọn maa ṣewadi daadaa nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si maa fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun.












Leave a Reply