alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ibo ọdun 2027: Ko sẹni to le di Aarẹ Tinubu lọwọ -Jibrin

Adewale adeoye

Ọkan pataki lara ọmọ ẹgbẹ oṣelu New Nigerian Peoples Party (NNPP) to n ṣoju ẹkun Bebeji/Kiri, nipinlẹ Kano, nileegbimọ aṣoju-ṣofin kekere l’Abuja, Ọnarebu Abdulmumin Jibrin, ti ni ko sohun kankan to le di Aarẹ Tinubu lọwọ lasiko ibo ọdun 2027. O ni Aarẹ lo maa wọle lai si idiwọ kankan fun un lasiko naa.

Ọjọruu, Wsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni narebu Jibrin sọrọ ọhun di mimọ nibi eto ori tẹlifiṣan kan l’Abuja. O ni ni toun o, oun ko ri ohun kankan to le di Tinubu lọwọ lati ma ṣe wọle sipo pada lọdun 2027, nitori pe oun nifẹẹ si i, awọn araalu naa si nifẹẹ si iṣakooso ijọba rẹ daadaa.

Bakan naa lo bẹnu atẹ lu ahesọ kan tawọn araalu kan n sọ pe awọn ara OkeỌya ko nifẹẹ si Aarẹ Tinubu. O ni eeyan tawọn ara OkeỌya nifẹẹ si ni, wọn yoo si dibo fun un lasiko ibo ọdun 2027.

Aṣofin yii ni, ‘‘Ko soootọ ninu pe awọn ara OkeỌya ko nifẹẹ si Aarẹ Tinubu, a wa lẹyin rẹ gbagbaagba ni, oun la maa dibo wa fun lasiko ibo ọdun 2027. Loootọ, awọn kọọkan lOkeỌya ko nifẹẹ si i, ṣugbọn awọn ti wọn nifẹẹ rẹ lo pọ ju awọn ti ko nifẹẹ si i. Bi asiko ibo ọdun 2027 ba ṣe n sun mọ, ẹ maa ri i pe awọn ara OkeỌya maa fifẹ han si Aarẹ Tinubu, wọn si maa dibo fun un’’.

O waa rọ awọn oloṣelu ẹya Hausa pe ki wọn ma ṣe dabaa lati dije dupo pẹlu Aarẹ Tinubu lasiko ibo ọdun 2027. O ni ki wọn jẹ ki ẹya Yoruba pari saa wọn tan ko too di pe wọn maa jade lati dije dupo aarẹ orileede yii lọdun 2031.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *