alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ibo ọdun 2027: Mi o ni i tako Aarẹ Tinubu o- Hadi Serika

Adewale adeoye

Minisita ọkọ oju ofurufu lorileede yii tẹlẹ, Hadi Serika ti bẹnu atẹ lu ahesọ tawọn kan n gbe kiri igboro pe o fẹẹ lẹdi apo plu awọn ẹgbẹ oṣelu alasopọ kan lati gbajọba lọwọ Aarẹ Tinubu lasiko ibo ọdun 2027. O ni ko sohun to jọ bẹẹ lọdọ oun o.

Ọjọruu, Wsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Hadi Serika toun naa jẹ minisita lasiko ijọba Buhari sọrọ ọhun di mimọ. O ni sidii kankan toun ṣe maa lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu alasopo lati gbajọba lọwọ Tinubu lọdun 2027.

O ni, ‘‘Aipe yii ni mo lọ siluu Abuja, lati lọọ ki Aarẹ, ṣugbọn ti Alukoro eto iroyin rẹ, Bayọ Ọnanuga beere lọwọ mi boya mo wa ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, lati gbajọba lọwọ ọga oun. Lojuẹsẹ ni mo ta ko ahesọ naa. Mo sọ fun un pe mi o si ninu ẹgbẹ oṣelu kankan to le di Aarẹ Tinubu lọwọ. Mi o ki i ṣe ọlọtẹ sijọba apapọ rara.

Bẹ o ba gbagbe, aipe yii ni awọn kan da ẹgbẹ oṣelu alasopo ADC silẹ, eyi ti wọn sọ pe ohun lawọn fẹẹ lo lati gbajọba lọwọ Aarẹ Tinubu lasiko ibo ọdun 2027. Alhaji Atiku Abubarkar to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ orileede yii lo ṣaaju idasilẹ ẹgbẹ oṣelu naa. Lara awọn ti wọn wa ninu ẹ ni Rotimi Amaechi, Alhaji El Rufai, Sẹnet David Mark, Rauf Arẹgbeṣọla atawọn oloṣelu jankanjankan mi-in lorileede yii.

Lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ lo ti sọ pe oun ki i e ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa, ati pe ko sohun toun n wa lọ sibẹ.

O fi kun un pe ki i ṣe nitori ti ajọ EFCC ṣe n ṣewadii oun nipa ẹsun iwa ọdaran kan ti wọn fi kan oun loun ṣe lọọ ba Aarẹ Tinubu l’Abuja.

Hadi Serika ni idi pataki toun ṣe lọọ ṣabewo si Aarẹ Tinubu ni lati ki i fun bo ṣe ṣe daadaa sawọn ọmọlẹyin Oloogbe Buhari lẹyin to ku tan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *