Florence Babaṣọla
Ẹwọn oṣu mẹta ni adajọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, ju Akeem Jimoh, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to tun lọọ jale leyin to tẹwọn de si. Adajọ ni ko maa pada lọ sibi to ti n bọ.
Akeem, to n ṣiṣẹ mẹkaniiki, ẹni ti ko pẹ to jade lọgba ẹwọn, ni wọn lo ji iṣu mẹtadinlogun ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogoji Naira gbe.
Agbefọba, Babatunde Olukokun, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
O ni lagbegbe Ataọja, niluu Oṣogbo, ni Akeem ti huwa ọhun, nigba ti ọwọ tẹ ẹ ni wọn fa a le awọn agbofinro lọwọ, ti wọn si wọ ọ wa si kootu.
Nigba ti wọn ka ẹsun ti wọn fi kan an si i leti, Akeem sọ pe loootọ loun jẹbi, ṣugbọn ki kootu ṣiju aanu wo oun pẹlu ileri pe oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ.
Ninu idajọ rẹ, Majisreeti Muibah Ọlatunji, ju u sẹwọn ọdun mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara lai fi aaye faini silẹ fun un rara.











Leave a Reply