Monisọla Saka
Awọn mọlẹbi agba oṣerebinrin ilẹ wa to padanu ọmọ ẹ laipẹ yii, Peju Ogunmọla, ati ọkọ ẹ, Sunday Ọmọbọlanle, tawọn eeyan mọ si Papi Luwẹẹ tabi Aluwẹẹ, ti sọrọ sita lori iku to pa ọmọ wọn, Ayọmikun, to jade laye lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Iroyin to gbode nigba naa ni pe inu baluwẹ lọmọ kan ṣoṣo ti oṣerebinrin yii bi ti yọ ṣubu, to si gbabẹ ku, nigba ti ko si ẹnikẹni nitosi lati ran an lọwọ.
Bẹẹ lawọn kan tun sọ pe ilu oyinbo lọmọkunrin to pari agunbanirọ rẹ laipẹ yii n gbe, oun nikan lo si wa ninu ile nigba to ṣubu ninu ile-iwẹ, airi ẹni ran an lọwọ lasiko lo si ṣokunfa iku ojiji ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun naa.
Amọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun mọlẹbi wọn, Yẹmi Amọdu, fi sita, lo ti jẹ ki ohun to ṣokunfa iku ọmọkunrin naa gan-an di mimọ fun gbogbo aye.
O ni yatọ si iroyin to n lọ kiri, ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, tawọn obi ẹ fi ṣe ibugbe, lọmọkunrin naa ku si, lẹyin aisan ranpẹ, o si fi kun un pe wọn ti sinku ọmọkunrin naa.
O ni, “Pẹlu ibanujẹ nla, ni a fi kede ipapoda ọmọ wa atata, Ṣọla Ayọmikun Ọmọbọlanle, ti i ṣe ọmọ Sunday ati Peju Ogunmọla Ọmọbọlanle. Ohun-ini iyebiye, ọmọ atata, ati irawọ to n tan, ti imọlẹ rẹ mọlẹ yòò, to si fi ran ọpọlọpọ eeyan. Adanu nla ni iku rẹ jẹ fun ẹbi wa ati gbogbo ẹni to mọ ọn, ti wọn si nifẹẹ ẹ.
“A fẹẹ sọ ọ di mimọ pe ki i ṣe pe Ṣọla ṣubu ninu baluwẹ lo ṣe jade laye o, gẹgẹ bi iroyin to n lọ nita. O kan ṣe aisan ranpẹ ni, laarin akoko ọhun si ree, itọju alailẹgbẹ gidi ni wọn fun un nileewosan. Ṣugbọn pẹlu gbogbo akitiyan tawọn ikọ dokita oniṣegun oyinbo naa ṣe, o pada jẹ ipe Ẹlẹdaa ẹ wọọrọwọ. Ile-iwosan kan niluu Ibadan, lorilẹ-ede Naijiria nibi, lo ti gbẹmii mi, wọn si ti filẹ bo o laṣiiri ni itẹkuu Eternal Rest Home.
“Lasiko ibanujẹ nla ati ọfọ yii, a dupẹ ifẹ ti ẹ fi han wa, a dupẹ adura ati atilẹyin ta a ri gba lọwọ ẹbi, ọrẹ, awọn alabaaṣiṣẹpọ atawọn afẹnifẹre gbogbo. Orisun agbara ati itunu ni iwa rere ati ifẹ ti ẹ fi han wa jẹ fun wa.
“A n gba a laduura pe idile kan bo ti wu ko mọ, ko ni i rogun iku ọmọ ati ololufẹ wọn lai tọjọ. Ki Ọlọrun Ọba ba wa tẹ Ṣọla si afẹfẹ rere, ki o si fun awa naa lokun lati gba ofo nla ti ko ṣee yipada yii mọra”.
Ka ranti pe gogoogo ni ilu kan, ti ori ayelujara paapaa si n ṣọfọ, nigba ti wọn kede iku ọmọkunrin toun ati mama ẹ fẹran ara wọn bii ọrẹ korikosun yii lọjọ Iṣẹgun.
Latigba naa lawọn ẹbi, ara, ọrẹ, ojulumọ, paapaa ju lọ awọn akẹgbẹ tọkọ–taya ti wọn jẹ oṣere yii ti n ranṣẹ ibanikẹdun si wọn, ti wọn si tun n lọọ ba wọn daro nile.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin oṣere adẹrin-in-poṣonu, Aluwẹẹ, ti i ṣe ọkọ Peju ati baba ọmọ to doloogbe yii ni awọn ọmọ mi-in, Ṣọla, ti mama ẹ maa n pe ni ‘My Happiness’ (Idunnu mi) yii, ni ọmọ kan ṣoṣo ti agba oṣere naa bi lẹyin ọpọ ọdun to ti n tọrọ oore lọdọ Ọlọrun.
Adura ti wọn n gba fun mama yii ni pe ki Ọlọrun rọ ọ lọkan, ki O gbe duro pada, ki O si wa pẹlu oun ati idile rẹ titi lae.











Leave a Reply