alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Eyi ni alaye ti Ibrahim Chatta ṣe nipa ọmọkunrin rẹ to ku

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Bi eeyan kan ba wa lori idubulẹ aisan, idaamu ọkan to maa n ba awọn eeyan rẹ ti wọn n tọju ẹ paapaa a maa ju ti alaisan funra rẹ lọ nigba mi-in. Iyẹn ni Yoruba ṣe maa n powe pe ara ko ni iwọfa bii onigbọwọ, abanikowo lara n ni. Bi ọrọ iku ọmọ gbajugbaja oṣere tiata nni, Ibrahim Chatta, Muhammed, to jẹ Ọlọrun nipe lọsẹ to kọja, ṣe ri gẹlẹ gan-an niyẹn.

 

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 yii ni Ibrahim Chatta funra rẹ tufọ iroyin ibanujẹ naa si ikanni ayelujara rẹ, to ni “Iwọ Ọlọrun, ọdọ rẹ la ti wa, ọdọ rẹ naa la o pada si, sun un re o, ọmọ mi aṣegun.”

 

Lẹsẹkẹsẹ lori ẹrọ ayelujara ti kun akunfaya fun iroyin iṣẹlẹ yii ati ọrọ ibanikẹdun ti awọn eeyan n kọ ranṣẹ  si ọkunrin naa onitiata naa.

 

Ko sẹni to gbọ iroyin iku Muhammed ti wọn pe lọmọ irawọ oṣere yii ti iṣẹlẹ naa ko ba lọkan jẹ, paapaa nitori pe ki i ṣe igba akọkọ leyi ti ọkunrin naa yoo padanu ọmọ rẹ. Ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii, niroyin gbe ọrọ iku akọbi rẹ jade nigba ti oun funra rẹ ranti iku ọmọbinrin rẹ naa.

 

Ṣugbọn nigba ti iroyin iṣẹlẹ yii ko jẹ ki ori ẹrọ ayelujara sinmi, ti awọn eeyan ko si jẹ ki oṣere tiata yii paapaa sinmi fun ọrọ ibanikẹdun, ipe ati atẹranṣẹ, lọkunrin naa jade sita lati ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ gan-an.

 

O ni loootọ, ọmọ oun lọmọ to ku yii, ṣugbọn ki i ṣe ọmọ to ti ara oun jade, ọmọ afẹnubi oun lasan ni, ṣugbọn iku rẹ ka oun lara gẹgẹ bii ẹni pe oun gan-an loun bi arẹwa ọmọkunrin naa ni.

 

Ninu fidio to fi ṣalaye ọhun lo ti darukọ ọmọkunrin naa gẹgẹ bii Muhammed, ti baba to bi i si n jẹ Oyekan, iyẹn ni pe Oyekan Muhammed gan-an lorukọ ti ọmọ naa n jẹ.

 

Gẹgẹ bii alaye to ṣe nibi fidio to gbe sori ẹrọ ayelujara naa, o ni, Nitori àsọyé ọrọ lo jẹ ki n ṣe fidio yii. Ṣẹ ẹ ri i, ofin kan wa ninu ẹsin Islam, ti eeyan ba gba ọmọ wo, eeyan ko gbọdọ yi orukọ awọn obi ọmọ naa pada, orukọ awọn obi ẹ naa lo gbọdọ maa jẹ lọ.

 

“Lakọọkọ na, mo fẹẹ dupẹ lọwọ awọn oloṣelu, awọn oṣere ẹgbẹ mi atawọn ololufe mi kaakiri, mo ri gbogbo ipe ati ateẹranṣẹ yin tẹ ẹ fi ba mi kẹdun ipapoda ọmọ to ku. Mo gbadura pe a o ni i fi aburu gba a o.

 

“Ṣugbọn mo fẹẹ ṣe fidio yii lati ṣalaye pe ọmọ ti Ọlọrun mu sọdọ yẹn, Muhammed Oyekan lorukọ rẹ, ki i ṣe ọmọ bibi inu mi, ọmọ àfẹnubí mi ni.

 

Awọn to ba ṣakiyesi ibaṣepọ mi pẹlu awọn ọmọde, yoo ri i pe bi mo ṣe ni awọn ọmọ bibi inu mi naa ni mo ni awọn ọmọ afẹnubi. Awọn ọmọ afẹnubi mi si pọ gan-an. Koda, a ri ninu wọn ti wọn jẹ akẹgbẹ mi nidii iṣẹ yii, ti wọn ti dagba, to jẹ pe ọrẹ mi ni mo wa n pe wọn bayii nitori pe awọn naa ti dagba, wọn ti di baale ile.

 

“Fun alaye, ko le ye awọn eeyan, ọmọ mẹta ni mo bi (o darukọ awọn mẹtẹẹta) ṣugbọn bi mo ṣe nifẹẹ awọn ọmọ ti mo fi ara bi yii naa ni mo fẹran awọn ti wọn jẹ ọmọ afẹnubi mi wọnyi naa. Idi niyẹn ti iku Muhammed yẹn ṣe ka mi lara.

 

Bakan naa ni ifẹ awọn ọmọ afarabi mi atawọn ọmọ afẹnubi mi ṣe ri lọkan mi. Ko si abiamọ kankan to tọ si pe ko padanu ọmọ rẹ. Mo gbadura pe ki Ọlọrun rọ awọn obi ọmọ naa loju.

 

“Gbogbo wa la ti mọ pe dandan ni iku, ṣugbọn ko sẹni to maa gbadura ki oun padanu ọmọ oun, ọmọ to yẹ ko da eepẹ bo oun loju lẹyin iku oun.”

 

Ibrahim Chatta tun gbadura fun Peju Ogunmọla

to padanu ọmọkunrin rẹ laipẹ yii, o ni ki Ọlọrun rọ agba oṣere naa loju.

 

Ta o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 yii, niroyin gba aye kan nipa bi Peju Ogunmọla ṣe padanu Ayọmikun, ọmọkunrin rẹ kan ṣoṣo to bi laye.

 

Bakan naa lọkunrin onitiata yii gbadura fun idile Ṣáńkú, ọmọkunrin to maa n ṣe awọn ere apanilẹrin-in lori ẹrọ ayelujara, ti oun naa padanu ẹmi ẹ sinu ijanba ọkọ lọsẹ to kọja.

 

Nigba to n darukọ diẹ ninu awọn eeyan nla ti wọn ti pe e lati ki i kuu atẹmọra iku ọmọ afẹnubi rẹ yii, Ibrahim Chatta dupẹ lọwọ minisita feto ibanisọrọ lorilẹ-ede yii nigba kan ri, Alhaji Lai Muhammed; baba oniwaasi nni, Buhari ọmọ Musa; pẹlu awọn gbajumọ oṣere bii Doyin Kukọyi, Fẹmi Adebayọ, Muyiwa Ademọla, Bimbọ Ọṣin, Madam Ṣajẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *