alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ọlọpaa ti ranṣẹ pe El-Rufai, eyi lohun ti wọn lo ṣe

Adewale adeoye

Ni bayii, olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, ti kan an nipa pe ki gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Mallam El-Rufai, atawọn mẹfa kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC yọju sileeṣẹ awọn lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan wọn. Wọn ni wọn gbọdọ waa ṣalaye fawọn nipa ija itẹjẹsilẹ kan to waye lasiko ti ẹgbẹ oṣelu naa n ṣepade ẹgbẹ wọn laipẹ yii nipinlẹ naa. jọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Ninu lẹta kan ti ọga agba ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinl naa, ẹka to n ri sọrọ iwa ọdaran, Uzainu Abdullahi, kọ si alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ naa lo ti pa a laṣẹ fun un pe ko ri i pe oun mu El-Rufai atawọn mẹfa kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa wa si olu ileeṣẹ wọn lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lati waa sọ tẹnu wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Awọn tileeṣẹ ọlọpaa ni ki wọn yọju ni: Mallam El-Rufai, Bashir Sa Idu, Jafari Sani Ubaidullah Mohammed, ẹni tawọn eeyan mọ si 30, Nasiru Maikano, Aminu Anita ati Ahmed Rufai Hussain, tawọn eeyan mọ si Mikiya.

Wọn ni ki gbogbo awọn eeyan naa yọju sileeṣẹ awọn lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lati waa ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ ibanujẹ kan to waye niluu naa lasiko ti wọn n ṣe ipade ẹgbẹ wọn nibi tawọn kan ti fara pa yannayanna.

Wọn ni iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye nitori awọn ọrọ ati iwa ọdaran tawọn afurasi ọdaran naa hu laarin ilu, ni eyi ti wọn bẹnu atẹ lu gidigidi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *