Ọlawale Ajao Ibadan
Getimaanu to n ṣọ ileewe aladaani kan nigboro Ibadan, ti dero atimọle ọlọpaa bayii nitori bo ṣe ba ọmọ kekere laṣepọ ni tipatipa.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o ti da ibẹru sọkan ọpọ obi to lọmọ nileewe ọhun bayii, wọn ni bi gende ọkunrin ba le fipa ba ọmọọdun mẹrin pere laṣepọ, ko si itu ti iru eeyan bẹẹ ko le fi awọn akẹkọọ ti wọn ti di ọmọge pa.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 yii, lawọn agbofinro lọọ fi panpẹ ọba gbe ọkunrin eni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ọhun, Josiah Ayọmide, to ba ọmọọdun mẹrin pere laṣepọ.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin loju ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣalaye pe, “Ko sẹni to mọ igba ti ọkunrin yii huwa buruku naa, afi lọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Kẹjọ, ọdun yii, nigba ti ọmọdebinrin yẹn sọ fun ẹgbọn rẹ obinrin nile pe oju ara n dun oun.
“Lẹyin ọpọlọpọ ibeere ti wọn bi i lo too ṣẹṣẹ ṣalaye fun iya ẹ nipa nnkan ti getimaanu wọn ṣe fun un nileewe to n lọ.
“Iyẹn lo jẹ ka mu ọkunrin getimaanu yẹn, o si ti wa lakata wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo bi mo ṣe n sọrọ yii.”
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu ọmọdebinrin naa lọ sileewosan fun ayẹwo, nibi tawọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ti ja ibale ọmọde ti ko da nnkan kan mọ naa.
Ayọmide ti wọn n fọrọ wa lẹnu wo lọwọ yii lo jẹ ọkan ninu awọn mẹtadinlogun (17), ti ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tẹ fun ẹsun iwa ọdaran loniran–n–ran.
Nibi ti nnkan de duro yii, ko ni i pẹ rara ti CP Fẹmi Haruna ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ yoo fi gbe afurasi ọdaran naa lọ si kootu fun ẹsun ifipabọmọdelopọ.
CP Haruna waa gba awọn obi atawọn olukọ nimọran lati maa mojuto awọn ọmọ wọn daadaa, ki wọn si yee gba wọn laaye lati maa da wa nibi ti oju wọn ko ti to wọn.











Leave a Reply