Monisọla Saka
Ko din ni oku eeyan bii ọgbọn, tawọn ajọ to n ri si ọrọ iṣẹlẹ pajawiri lorilẹ-ede yii, National Emergency Management Agency (NEMA), ti ri ko jade bayii, nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to waye niluu Gausawa, ijọba ibilẹ Borgu, nipinlẹ Niger.
Ninu ọkọ oju omi to doju de, tawọn eeyan aadọrun-un wa ninu ẹ, to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni ajọ NEMA ti sọ pe mejidinlọgọta ninu awọn ero naa lawọn ti ribi doola, eeyan kan tawọn tun ribi gbe jade lo jẹ ki oku eeyan tawọn ri di ọgbọn.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Manzo Ezekiel, ti i ṣe akọwe iroyin fun ajọ NEMA, sọrọ naa di mimọ ninu atẹjade to fi sita.
O ni adari agba ajọ NEMA, Arabinrin Zubaida Umar, ti ni ki ileeṣẹ NEMA to wa niluu Minna, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Niger, tẹra mọ wiwa awọn eeyan to wa nisalẹ omi naa jade.
O ni, “Awọn ti wọn wa nibi iṣẹlẹ ijamba naa sọ pe awọn ero bii aadọrun-un ni ọkọ oju omi naa ko. Lọwọ bayii, eeyan mejidinlọgọta ni wọn ti doola, ẹmi to le ni ọgbọn lo ti ṣofo, nitori wọn tun ri oku kan si i lọsan-an ọjọ Tọsidee. A o ti i le sọ iye awọn yooku tabi ipo ti wọn wa gẹgẹ bi wọn ṣe n ba iṣẹ lọ lori bi wọn ṣe n wa wọn.
“Iwadii fidi ẹ mulẹ pe apọju ero lori ọkọ oju omi naa ati oku igi kan to wa labẹ omi ti ọkọ oju omi ọhun lọọ lari mọ, lo ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba naa.
“Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, Niger State Emergency Management Agency (NSEMA), ni wọn ṣaaju bi wọn ṣe n doola awọn eeyan ọhun pẹlu awọn eekan mi-in bii ileeṣẹ to n ri si irinna ori omi,(National Inland Waterways Authority), ileeṣẹ to n ri si ọrọ ina mọnamọna latinu omi, Ẹgbẹ aladaani Alagbelebu Pupa, Nigerian Red Cross Society, awọn omuwẹ atawọn araalu ti wọn jọwọ ara wọn silẹ fun iṣẹ aanu naa.
O ni ajọ NEMA n ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ tọrọ kan lati ri i pe gbogbo ẹ kẹsẹ jari laipẹ ọjọ.
O ṣalaye pe, ‘’O ṣe pataki ki a mọ pe, oni yii kọ ni iṣẹlẹ ijamba oju omi ti n waye, paapaa lawọn agbegbe ti wọn ti n fi oju omi ṣe ẹsẹ rin.
Lara awọn ohun ti wọn lo n ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba yii ni ero to n papọju lori ọkọ, aitẹle ofin irinna, ọkọ oju omi ti ko dangajia atawọn ohun eelo to n dena ijamba ti ko to fun wọn.











Leave a Reply