alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ọkunrin yii ti jẹwọ: Loootọ ni mo mọ nipa iku iyawo mi ti wọn pa n’Ilọrin

Monisọla Saka

 

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Kwara, ti tẹ Ekene Enemor, ọkọ Abilekọ Esther Enemor, obinrin ti wọn ge ara ẹ lekiri lekiri lẹyin ti wọn gbẹmi ẹ tan, lagbegbe Egbejila, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara. Lasiko tọwọ tẹ ọkunrin yii ni wọn sọ pe o jẹwọ pe loootọ loun mọ nipa iku ẹ, ṣugbọn oun ko sọ pe ki wọn kun un si wẹwẹ.

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fidi ẹ mulẹ pe Ekene sọ pe oun loun ni ki wọn pa iyawo oun ti wọn tun mọ si Iya Ibeji yii, ṣugbọn to iyalẹnu lo jẹ pe wọn ge ara ẹ lekiri lekiri.

 

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo, to sọrọ naa di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii, lasiko ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ati aṣeyọri ileeṣẹ wọn fun oṣu to kọja yii, sọ pe agbegbe Egbejila, niluu Ilọrin, nibi ti Oloogbe Esther Enemor n gbe, ni wọn ti pa a.

 

Ọga ọlọpaa yii ni aladuugbo kan to fura si ọrọ naa, iyẹn Ahmed Salman, to ke gbajare sawọn araadugbo lẹyin to ri ẹni kan to n tilẹkun ile awọn Enemor sita, nigba ti Esther wa ninu yara ni tiẹ ni Ọlọrun fi tu aṣiri ọrọ ọhun.

 

Nigba ti wọn da a duro lati beere ibi to ti wa ati ohun to n fẹ, o ni aburo Ekene, toun pẹlu awọn ẹbi ẹ n gbe labule Moshe Gada, agbegbe Kaiama, nipinlẹ Kwara loun.

 

Ṣugbọn gbogbo alaye tọkunrin yii ṣe ko tẹ Salman lọrun, eyi lo mu ki o kan ilẹkun, ṣugbọn ti ko gbọ idahun ẹnikẹni. Bo ṣe taju kan-an, to ri ẹjẹ lara ogiri fẹnsi ile wọn niyẹn. Nibi yii gan-an lo ti pe gbogbo araale atawọn araadugbo lati jade sita waa wo nnkan toun ri.

 

Nibi ti wọn ti n wa ayika ibẹ kiri ni wọn ti ri ẹya ara Esther, ti wọn ti ge lati ibi ọrun titi de ibadi, ti ori ati apa ẹ si ti dawati.

 

Lasiko ti wọn tun n gbọn gbogbo ayika yẹbẹyẹbẹ ni wọn ri ẹya ara mi-in to jẹ lati ibadi debi itan, ti wọn fi pamọ si abẹ palapala kan, ṣugbọn ti ko si ẹsẹ kankan nibẹ naa, eyi ti wọn lo mu ifura dani pe o ṣee ṣe ko jẹ owo karakata ẹya ara eeyan, tita ẹya ara eeyan siluu mi-in tabi lati lo o fun oogun dudu ati etutu owo ni.

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ni lasiko tawọn gbe iwadii dide lori ọrọ yii lawọn lọọ gbe Ekene Enemor, to pada jẹwọ pe oun loun pa iyawo oun, ti wọn tun mọ si Iya Ibo lagbegbe naa.

 

“Ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ọkunrin kan to n jẹ Ahmed Salman, to n gbe lagbegbe Temidire 6, Egbejila, niluu Ilọrin, lọọ ba awọn agbofinro teṣan Budo Nuhu, pe ni nnkan bii aago mẹfa aabọ idaji ọjọ ọhun kan naa, oun ko ẹni kan loju nigba to n tilẹkun araale oun kan pa, nigba ti iyawo araale oun, ti wọn n pe ni Iya Ibeji ṣi wa ninu ile sibẹ.

 

“Ẹni yẹn darukọ ara ẹ, bẹẹ lo sọ ọ di mimọ pe aburo ẹni to nile, iyẹn Ọgbẹni Ekene Enemor, to n gbe labule Moshe Gada, to loju ọna Kaiama, nipinlẹ Kwara, pẹlu awọn ẹbi ẹ, loun n ṣe.

 

“Ọgbẹni Ahmed Salman, ti alaye ọkunrin yii ko tẹ lọrun to sun mọ ibi ilẹkun naa, o kan an titi, ṣugbọn ko gbọ ìjẹ́ ẹnikan. O pariwo orukọ Abilekọ Esther titi, ṣugbọn ko gbọ idahun.

 

“Ẹnu eleyii ni wọn wa nigba to ri ipa ẹjẹ lara fẹnsi ati ara ogiri ile wọn. Nitori bẹẹ lo ṣe kibosi fawọn araadugbo.

Nigba ti wọn yẹ gbogbo ayika ile naa wo, ni wọn ri ẹya ara Arabinrin Esther, lati ọrun de ibadi, lai si ori ati ọwọ mejeeji nibẹ.

 

“Nigba ti wọn tubọ yẹ gbogbo ayika ile naa wo daadaa ni wọn ri ẹya ara ẹ mi-in, lati ibadi de itan, ti wọn tọju pamọ si abẹ ibi kan nibẹ, lai si ẹsẹ mejeeji nibẹ.

 

“Lẹyin ti wọn fẹjọ ọrọ yii sun ọlọpaa tan, ni wọn kan si ọkọ oloogbe labule Moshe Gada, Kaiama, ti wọn si fi panpẹ ofin gbe aburo ọkunrin afurasi naa, to tun jẹ aburo ọkọ oloogbe, iyẹn Sylvester Enemor.

 

“Wọn ti taari ẹjọ yii lọ si CID, iyẹn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n wadii ẹsun ọdaran, fun iwadii to jinlẹ”.

Bo tilẹ jẹ pe afurasi kọkọ yari pe oun ko mọ nipa ẹ, nitori ilu Kaiama, loun wa laaarọ ọjọ tiṣẹlẹ naa waye, awọn to ṣewadii yii ni niṣe lawọn ọmọ ẹ ta ko o pe irọ lo n pa.

Ẹyin-ọ-rẹyin lo jẹwọ pe iṣẹ ọwọ oun ni, ṣugbọn oun ko sọ fun wọn pe ki wọn kun un wẹlẹwẹlẹ.

 

O ni lẹyin ti wọn fi panpẹ ofin gbe ọkọ oloogbe tan, lasiko ifọrọwanilẹnuwo lo jẹwọ pe oun lọwọ ninu iku iyawo oun.

 

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi kun ọrọ wọn pe afurasi ko ri opin ẹjọ naa, nitori lasiko ifọrọwanilẹnuwo ni wọn ni aisan buruku kan rọ lu u, ileewosan si ni ọkunrin ti wọn ko ridii aisan to n ṣe e yii ti pada gbẹmii mi.

 

Kọmiṣanna ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, bẹẹ ni akitiyan n lọ lati wa awọn afurasi yooku ti wọn gbagbọ pe wọn ti na papa bora ni awari.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *