Monisọla Saka
Ileeṣẹ eto irinna oju irin lorilẹ-ede yii, The Nigerian Railway Corporation (NRC), ti fofin de reluwee to n na Abuja si Kaduna, lai ni gbedeke igba ti yoo wa sopin.
Ikede yii jade lẹyin ijamba to ku diẹ ko mu ẹmi ọpọ eeyan lọ to waye laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Ogunlọgọ awọn ero inu tireeni naa lori ko yọ lọwọ iku ojiji, nigba ti ẹsẹ tireeni to gbera laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, naa yẹ kuro lori irin, ti awọn ojule ẹlẹkajẹka inu tireeni naa (Coach), yẹ danu, tawọn mi-in si dori kodo.
Iṣẹlẹ to ko jinnijinni ba awọn ero inu ọkọ yii lo mu ki Ọgbẹni Kayọde Ọpẹifa, ti i ṣe adari agba nileeṣẹ reluwee, (NRC) kede lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, pe awọn ti fofin de tireeni ọhun, titi kan gbogbo awọn to n na Kaduna si Abuja bayii na.
O ni awọn oṣiṣẹ to jẹ mọ iṣẹ ẹrọ nileeṣẹ NRC atawọn ti ileeṣẹ to n ri si eto aabo nilẹ Naijiria, Nigeria Safety Investigation Bureau (NSIB), to fi mọ awọn ileeṣẹ ijọba mi-in tọrọ kan, ti kọja si ibudo iṣẹlẹ naa lati wadii ohun to ṣokunfa ijamba ọhun.
O sọrọ siwaju si i pe mẹfa ninu awọn ero inu reluwee yii ni wọn farapa diẹ, ti wọn si ti tọju wọn.
Ileeṣẹ yii ni awọn ero okoolelẹgbẹta o din meji (618), ni wọn wa ninu ọkọ oju irin to fẹẹ danu nitosi ibudokọ oju irin Asham yii, ati pe gbogbo igbesẹ lawọn n gbe lati ri i daju pe awọn da owo awọn ero inu ọkọ naa pada fun wọn.
Ọpẹifa ni irọ to jinna si ootọ ni pe ẹgẹrẹmiti ni tireeni ọhun, o ni ko si nnkan kan to ṣe e.
O ni, “Ileeṣẹ NRC ti fidi ijamba tireeni to yẹ gẹrẹ lori irin mulẹ ninu ọkọ oju irin wa to n na Kaduna, ni nnkan bii aago mọkanla kọja iṣẹju mẹsan-an aarọ ni agbegbe kilomita kọkandinlaaadọta, to wa laaarin ibudokọ Kubwa si Asham.
“Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pajawiri, awọn oṣiṣẹ eto ilera ati ọsibitu to wa nitosi ni a ti ko debẹ. Bakan naa lawọn ẹṣọ alaabo ti wa nibẹ gẹgẹ bi akitiyan lati ko awọn ero naa pada si Kaduna lalaafia ṣe n lọ”.
Hajiya Zubaida Umar, ti i ṣe ọga agba ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹ-ede yii, iyẹn National Emergency Management Agency (NEMA), lo ṣaaju awọn oṣiṣẹ pajawiri ileeṣẹ wọn lọ sibudo iṣẹlẹ naa.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ NRC kan to ba The Nation sọrọ sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ole to maa n ji nnkan yọ loju irin tabi nitori bi wọn ko ṣe de irin ọgangan iṣẹlẹ yẹn daadaa lo fa ijamba naa.
Owuyẹ kan toun naa sọrọ lori ohun to ṣee ṣe ko fa eleyii sọrọ, o ni, “Gẹgẹ bi oṣiṣẹ wọn kan to wa nibudokọ oju irin Asham ṣe sọ, ibi igun kan lori oju irin yẹn ni wahala ti bẹrẹ. Ibi kan wa tawọn oju irin yẹn ti pade, ti wọn ja pọ, ibẹ yẹn gangan ni. Nitori a ni awọn oju ila yẹn bii akọkọ, ila keji, oju ila kẹta.
“Ti wọn o ba waa ṣe oju ila yii daadaa, ti tireeni wọnu ẹ, o maa ṣubu ni. Nitori naa, bakan meji lọrọ yii, ninu ko jẹ pe wọn fọwọ ba a ni tabi ko jẹ pe wọn o ṣee daadaa sibẹ”.
Wọn ni iwadii ṣi n lọ lati mọ boya awọn to n ji nnkan lo fọwọ ba a nitori tireeni kan ṣi kọja nibẹ lọwọ aarọ ki eyi to nijamba too kọja. Wọn ni awọn o ti i le sọ boya nigba ti tireeni akọkọ yẹn n kọja lo bajẹ ni tabi nnkan mi-in lo fa a.
Bakan naa lawọn adari nileeṣẹ yii sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ iṣẹ ọwọ awọn ọta ijọba ipinlẹ naa tabi iwa aibikita awọn oṣiṣẹ to yẹ ki wọn tun ibi tawọn oju irin yẹn ti pade ṣe ni, nigba to ti jẹ pe ọwọ ni wọn fi n ṣe e.












Leave a Reply