alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Ijiroro n lọ labẹnu lati jẹ ki Obi, Jonathan pada waa dupo aarẹ lọdun 2027- Sẹnetọ Moro

Adewale Adeoye

Ọkan pataki lara ọmọ ile igbimọ aṣofin agba l’Abuja, to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Abba Mórò, ti ni ijiroro n lọ labẹnu laarin awọn alaṣẹ ẹgbẹ PDP nipa bi wọn se maa bẹ Ọjọgbọn Jonathan, to ti figba kan jẹ aarẹ orileede yii tẹlẹ, ati Peter Obi, toun naa dije dupo aarẹ lọdun 2023, labẹ ẹgbẹ Labour Party (LP), lati pada sinu ẹgbẹ naa. O ni o ṣe pataki pupọ pe ki awọn oloṣelu mejeeji naa pada sinu PDP, kawọn baa le ri oloṣelu gidi to maa koju Aarẹ Tinubu lasiko ibo ọdun 2027.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni Mórò sọrọ ọhun di mimọ l’Abuja.

O ni, ‘Bi a ṣe n sun mọ ọdun 2027, bẹẹ lawọn igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ PDP naa n gbiyanju gidi lati pari ija to ti fọ ẹgbẹ naa si meji tẹlẹ. Lara awọn ohun tawọn oloye ẹgbẹ naa n ṣe labẹnu lọwọ bayii ni pe wọn n gbiyanju lati pe jọgbọn Jonathan ati Obi, pada sinu ẹgbẹ PDP, ko too di asiko ibo ọdun 2027. gbẹ naa n wa awọn oloṣelu jankanjankan ti wọn lorukọ gidi laarin ilu to maa dije dupo aarẹ orileede yii lọdun 2027 ni.

ni o ṣee ṣe ki Jonathan pada sinu ẹgbẹ PDP laipẹ yii, awọn kan n ba a sọrọ lọwọ pe ko pada, nitori pe ẹgbẹ PDP lo sọ ọ di aarẹ orileede yii tẹl.

Bẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ PDP lo sọ Ọjọgbọn Jonathan di aarẹ orileede yii lati ọdun 2011 si 2015. Oun si ni aarẹ akọkọ to maa gbejọba silẹ fun alatako rẹ. O padanu ipo naa sọwọ Oloogbe Buhari lọdun 2025.

Ni ti Obi, oun naa jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ PDP tẹlẹ, koda ẹgbẹ yii lo sọ ọ di gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, bakan naa lo ti figba kan jẹ igbakeji fun Alhaji Atiku Abubakar lasiko ibo 2019, ko too di pe o lọ sinu ẹgbẹ Labour lati dije dupo aarẹ lọdun 2023.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *