alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Lori ọrọ ti ko to nnkan, ọkọ lu iyawo rẹ pa l’Ekiti

Olusẹyẹ Iyiade

 

Abilekọ kan ti wọn porukọ rẹ ni Modupẹ Alasin, ni wọn lo ti dero ọrun ọsangangan bayii lori lilu ti ọkọ rẹ lu u lalubami.

 

Iṣẹlẹ yii waye ninu oko wọn to wa niluu Ẹfọn Alaye, to jẹ ibujoko ìjọba ibilẹ Ẹfọn Alaye, nipinlẹ Ekiti, nibẹrẹ ọsẹ ta a wa ninu rẹ yii.

 

Ninu alaye ti araadugbo kan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ ṣe fawọn oniroyin, o ni ọrọ kekere kan lo da ede aiyede silẹ laarin tọkọtaya ọhun ko too di pe eṣu ba wọn lọwọ si i titi ti ọkunrin yii fi binu lu iyawo rẹ pa.

 

Ẹsun to ni ọkọ iyawo ọhun fi kan aya rẹ ninu oko lọjọ ta a n sọrọ rẹ yii ni pe o ti pẹ ju ko too waa ba oun nibi ti oun ti n ṣiṣẹ.

 

Gbogbo alaye ti Modupẹ ṣe lati fi tu ọkọ rẹ loju lo ni ko wọ ọkunrin naa leti rara, kaka ko sì tẹtí si obinrin naa, pasan nla kan lo fa yọ, eyi to fi na an titi to fi tẹ ifẹ inu ara rẹ.

 

Wọn ni obinrin yii kigbe titi, ṣugbọn ko rẹni gba a silẹ, bẹẹ ni gbogbo ẹbẹ to n bẹ ọkọ rẹ ko tu irun kan rara lara rẹ pẹlu bi ko ṣe tori eyi da ọwọ lilu to n lu u duro.

 

Lẹyin to lu iyawo rẹ nilukulu tan lo ṣẹṣẹ waa paṣẹ fun un lati lọọ pọn omi wa ninu odo kan ti ko fi bẹẹ jinna si oko wọn.

 

Omi yii la gbọ pe o n pọn lọwọ lẹbaa odo naa to fi ubu lulẹ lojiji, to si gbabẹ ku patapata latari awọn ibi to fi ṣeṣe nigba ti ọkọ rẹ n lu u.

 

Nigba to n fi idi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, ni awọn ti fi panpẹ ofin gbe ọkọ oloogbe ọhun, to si wa nibi ti awọn agbofinro ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *