Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ lorilẹ-ede yii tẹlẹ, to tun dupo Aarẹ lẹgbẹ PDP lasiko ibo aarẹ ọdun 2023, Alaaji Atiku Abubakar, ti ni pẹlu gbogbo akitiyan ẹgbẹ oṣelu to wa nipo, iyẹn All Progressives Congress (APC), lati yẹpẹrẹ awọn, ki wọn si dabaru gbogbo eto ẹgbẹ awọn ni ADC, ẹgbẹ alasopọ awọn yii maa jọ wọn loju lasiko ibo ọdun 2027.
Tunde Olusunle, ti i ṣe ọkan ninu awọn agbẹnusọ Atiku lasiko ibo ọdun 2023, lo sọrọ yii di mimọ fun iwe iroyin ThisDay.
O ni nnkan ti ọga oun atijọ n tẹnumọ, to si n duro le lori naa ni pe awọn gbọdọ gba Naijiria kalẹ kuro ninu ahamọ foni–ku–fọla–dide ti ijọba Bọla Tinubu ko o si.
Bakan naa ni Atiku ni kawọn eeyan ma lọ ro o, ki wọn ma si ṣe gba ahesọ ọrọ to n lọ nigboro pe oun ko ni i dupo aarẹ gbọ o, o ni oun maa gbegba ibo llọdun 2027, oun yoo si moke.
Atiku to fi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), to n ṣe silẹ, toun atawọn oloṣelu jankanjankan lati awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri si jọ pawọ–pọ da ẹgbẹ oṣelu alasopọ silẹ, eyi ti wọn ko lọ sinu ẹgbẹ to n jẹ African Democratic Congress (ADC), to si mu ki ẹgbẹ oṣelu naa wa nipo kẹta lọwọ bayii lẹyin APC ati PDP, ti sọ pe ọna lati gbajọba lọwọ Tinubu to n ṣelu baṣubaṣu lawọn ṣe gbe ẹgbẹ tuntun naa kalẹ fun oun lati le depo aarẹ.
Atiku ni iru ole buruku ti wọn n ja ninu ijọba to wa lode yii ki i ṣe kekere, ati pe o ti di dandan bayii fawọn lati doola Naijiria kuro lọwọ awọn adari to wa nibẹ.
O ni awọn maa ko awọn ọmọ Naijiria jọ lati gbajọba lọdun 2027, oun si ti ṣetan lati fa ara oun kalẹ lati ṣiṣẹ atunṣe naa.
“Gbogbo ẹtan buruku, iyi ati ẹyẹ to ti bọ sọnu, ole ojukorokoju ati aisi akọsilẹ fun gbogbo nnkan to n lọ, tawọn funra wọn ko si le duro deede lati ṣe ohun to tọ, ti ko si yẹ ko maa daamu ọkan awọn ọmọ Naijiria tootọ ti wọn fẹran ilu wọn denu, ma a fara mi silẹ lati ṣaaju awọn to fẹẹ gba orilẹ-ede yii pada, ti a o si ṣe atunṣe Naijiria to wa ninu iporuru ọkan”.
Olusunle to gbẹnu Atiku sọrọ yii sọ pe ọkunrin Waziri Adamawa naa sọ pe ẹgbẹ alasopọ toun jẹ adari fun yii wa lati wa atilẹyin to tọ fun awọn lati gba Naijiria kalẹ ninu ọfin to wa.
“ADC ti n ko awọn eeyan jọ, to maa mi agbaye titi. A maa gbarada mọ wọn lọwọ lọna to maa jẹ ijọloju fawọn to n ṣiyemeji nipa wa”.
Bakan naa ni Atiku ni irọ nla ni pe oun ko fẹẹ dupo Aarẹ mọ, tabi pe ki i ṣe dandan ni koun dupo aarẹ lọdun 2027.
Bo tilẹ jẹ pe Peter Obi, ti i ṣe gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ati oludije sipo aarẹ lẹgbẹ Labour Party lọdun 2023, ati Rotimi Amaechi, ti i ṣe gomina Rivers tẹlẹ naa ti fi erongba wọn han lati dupo aarẹ lẹgbẹ ADC, Atiku ki i yee pariwo pe oun loun dantọ ju fun ipo naa, bẹẹ ni Obi naa loun ko le ṣe igbakeji fun ẹnikẹni.
Tẹ o ba gbagbe, Olusunle ninu ọrọ ti Ọjọgbọn Ọla Ọlatẹju sọ lorukọ Waziri Adamawa yii nibi ayẹyẹ ikini kaabọ awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun nipinlẹ Eko, lo ti sọ pe Atiku ni oun ko sọ pe oun fẹẹ depo aarẹ ni dandan, ati pe ki i ṣe dandan ni ki oun dupo aarẹ, ṣugbọn Atiku ni ki i ṣe iṣẹ ti oun ran Ọlatẹju lo jẹ.
Atiku ni oun ati Ọlatẹju ko sọ gbogbo nnkan to gbe jade yẹn, ki i si i ṣe lati ọwọ oun. O ni, “Ma a gbegba ibo lọdun 2027. A gbọdọ gba Naijiria kalẹ lori akete aisan to wa. A ko ni i faaye gba bi nnkan ṣe daru lorilẹ-ede yii, bi iṣẹ, ebi, iya ati inira ṣe mu wa lomi”.
Atiku tun fesi si yẹyẹ igba gbogbo tawọn ẹgbẹ APC maa n fi wọn ṣe, ti wọn ni ẹṣin inu iwe lasan lasan ni ADC, wọn ko si le rọna lọ lọjọ ibo. O ni oju gbogbo aye ni yoo ṣe, nitori awọn maa ya gbogbo wọn lẹnu nigba tawọn ba ko gbogbo ibo lọdun 2027.












Leave a Reply