alaroye

iwe iroyin yoruba

Advertisement

Eyi ladehun to wa laarin Gomina Adeleke ati Ọba Ladọja

Ọlawale Ajao

Pẹlu bi gbogbo aye ṣe n foju sọna fun ọjọ iwuye gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Ọba Rashidi Ladọja, gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti jẹ́jẹẹ̀ẹ́ atilẹyin rẹ fun ọba tuntun naa pẹlu ileri pe oun funra oun yoo wa nikalẹ lati kopa nibi eto iwuye ọba yii.

 

Gomina Adeleke sọrọ yii lasiko abẹwo to ṣe si Ladọja nile ẹ to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

 

Nigba to n ki gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ naa kuu oriire fun bi Ọlọrun ṣe da a si, to fi gun akasọ agbega oye si ipo Olubadan, Adeleke ṣepejuwe ọba tuntun naa gẹgẹ bii apẹrẹ rere fun eto iṣejọba rere.

 

O ni “Kabiesi, awokọṣe rere lẹ jẹ lawujọ, apẹẹrẹ rere tẹ ẹ fi lelẹ lasiko iṣejọba yin gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ, lemi n lo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun.

 

“Mo gba a ladura pe ki Ọlọrun fi alaafia, ayọ ati ẹmi gigun ta yin lọre lori aleefa ipo ti ẹ fẹẹ bọ si yii.”

 

Yoruba bọ wọn ni bi awo ba ki funni, niṣe la a ki fun awo pada. Bi Adeleke ati Ladọja ṣe fọrọ ipade wọn ṣe lọjọ naa ree pẹlu bi Ladọja paapaa ṣe ni oun n fi oju sọna pe ki gomina naa ṣe saa keji nile ijọba, nitori pe ijọba rẹ n ṣe daadaa.

 

O ni inu oun maa n dun lati gbọ bi ijọba Adeleke ṣe n ṣe daadaa fawọn ara ipinlẹ Ọṣun, eyi lo sí jẹ ki oun maa foju sọna fun saa keji ọkunrin naa nipo ijọba, ko le tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ rere to n ṣe.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Ladọja ni, Gbogbo igba ti mo ba ti n gbọ iroyin nipa iṣẹ rere ti ijọba rẹ n ṣe nipinlẹ Ọṣun ni inu mi maa n dun, nitori pataki ijọba naa ni lati mu igbe aye irọrun ba araalu.

 

“Bi Ọlọrun ba ba ọ ṣe e to o ba wọle idibo gomina to n n bọ, lọjọ ti wọn ba maa bura fun ẹ fun saa keji nipo gomina, emi funra mi maa waa nibẹ lati fi ijokoo mi yẹ ọ si gẹgẹ Olubadan ilẹ Ibadan.

 

Gomina Adeleke pẹlu diẹ ninu awọn igbimọ alaṣẹ ijọba rẹ ni wọn jọ kọwọọrin fun abẹwo si ile Ladọja. Lara wọn ni Akọwe ijọba rẹ, Ọnarebu Teslim Igbalaye; Olori awọn oṣiṣẹ rẹ,

Alhaji Kazeem Akinleye; Yeyelua Modupeola Sanni-Adeleke, ti i ṣe Yeyelina ilẹ Ẹdẹ, pẹlu diẹ ninu awọn kọmiṣanna ijọba ipinlẹ Ọṣun.

 

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 yii, ni Ladọja yoo dade, ti yoo si gba iweẹri ati ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan kẹrinlelogoji (44)

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *