Wahala niluu Ikirun: Wọn yinbọn pa  omọọba, wọn tun dana sun aafin  

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Niṣe lọrọ di bo o lọ o yago niluu Ikirun Agunbẹ onilẹ obi, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla yii, lasiko ti awọn ọlọpaa fẹẹ fi tipatipa ṣi aafin Akirun ti awọn ọdọ ilu ti pa lati ọsẹ diẹ sẹyin. Nibi rogbodiyan naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan ninu awọn ọmọọba lati idile Gbolẹru, Lukman Ọmọọla Ọlatunji. Ọpo awọn ọmọ ilu naa ni wọn ti sa kuro niluu bayii, onikaluku ti wabi fori pamọ si.

ALAROYE gbọ pe awọn ẹṣọ alaabo kan, ninu eyi ti awọn ṣọja ati ọlọpaa wa ni wọn ya wọ aafin naa laaarọ ọjọ Wẹsidee, ti wọn fẹẹ fi tipatipa ṣilẹkun ibẹ. Ṣugbọn awọn ọdọ ilu ya bo ibẹ, wọn ni ko si ohun to jọ ọ. Ninu awọn ọdọ naa ni ọkan ninu awọn ọmọọba lati idile Gbolẹru, Lukman Ọlatunji. Wọn ni ọmọkunrin naa gbọ pe awọn kan fẹẹ fi tipatipa wọ aafin lo fi sare lọ sibẹ, eyi to fa ikọlu laarin oun atawọn agbofinro pẹlu awọn eeyan ilu mi-in. Lasiko naa ni awọn agbofinro bẹrẹ si i yinbọn soke lati fi le awọn eeyan to n di wọn lọwọ ọhun, nigba ti wọn yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ibọn ti ba ọmọọba naa, o si ku loju-ẹsẹ.

Ibinu ọrọ yii ni a gbọ pe awọn kan tinu n bi lori iṣẹlẹ yii fi gba ọna ẹyinkule aafin lọ, ti wọn si sọna si i.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn janduku to wa nibẹ n le awọn panapana ti wọn pe pe ko waa pana naa sẹyin, ti wọn si doju ija kọ wọn. Lasiko naa ni mẹta ninu awọn oṣiṣẹ panapana yii fara pa. Niṣe ni wọn sare gbe wọn lọ sileewosan.

Koju ma ribi, ẹsẹ loogun rẹ ni awọn araalu fọrọ naa ṣe, kaluku lo sa kuro niluu, nitori ohun to le tidi iṣẹlẹ naa yọ.

Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti wahala ti n lọ ninu ilu naa lori ẹni ti wọn yan gẹgẹ bii Akirun tuntun, Ọba Yinusa Akadiri.

Bi ijọba Oyetọla ṣe kede rẹ gẹgẹ bii ọba ko dun mọ awọn araalu atawọn idile ọlọmọọba yooku ninu. Wọn ni ẹni ti wọn yan ko tọ si ipo naa, ati pe ẹjọ kan wa ni kootu lori ọrọ ọba ilu ọhun.

Awọn eeyan naa lọọ fẹhonu han si ijọba pe ko rọ ọba naa loye nikan ni alaafia fi le jọba.

Lasiko ti wahala naa n lọ lọwọ lawọn ọdọ lọọ tilẹkun aafin pa, ti wọn si gbe ẹbọ ati oogun abẹnugọngọ sẹnu ọna ibẹ, ti wọn ni ko sẹni to gbọdọ wọlẹ.

Bakan naa ni awọn ọmọ igbimọ majẹ-o-bajẹ ilu Ikirun ti wọn n pe ni Akinrun-in-Council, ke si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja lori ọrọ yii, wọn ni ko pa ero rẹ lori iyansipo Ọlalekan Akadiri tijọba gbe ọpa aṣẹ fun gẹgẹ bii Akinrun ti ilu Ikirun da, wọn ni ko rọ ọ loye kia.

Ọjọgbọn Yakub Fabiyi to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ awọn ọmọ igbimọ ti wọn jẹ ọgọrin ninu mejidinlaaadọrun-un naa, ṣalaye pe bi Oyetọla ṣe yan Akinrun tuntun lai fi ti ẹjọ to wa ni kootu ṣe jẹ titapa si aṣẹ ile-ẹjọ. O waa gba gomina niyanju lati ṣe ohun to tọ, ko ma baa fi ọwọ pa ida ofin loju, ko si tete yọ Ọba Akadiri kuro nipo naa.Wọn ṣalaye pe idile mẹta lo n jọba: Ile Ọbaara, ile Adedeji ati ile Gbolẹru. Ile Ọbaara ni Adeyẹmi, Akinrun ijẹta ti wa, ile Adedeji ni Ọlayiwọla to gbesẹ ti wa, nitori naa, ile Gbolẹru lo kan lati fa ọmọ oye silẹ, awọn idile Gboléru si ni oniruuru ẹjọ ni kootu lọwọlọwọ.

Ẹni kan to ba ALAROYE sọrọ ti ko fẹ ka darukọ ohun ṣalaye pe niṣe ni ọba naa n wa gbogbo ọna lati ri i pe oun pada sinu aafin ki ọjọ iṣejọba Gomina Oyetọla to yan an sipo too tẹnu bọpo, nitori eyi nikan lo le fidi iyansipo rẹ mulẹ.

O ni eyi lo fa a ti awọn eeyan naa fi ko awọn agbofinro loriṣiiriṣii lẹyin, ti wọn si fipa jalẹkun aafin naa, leyii ti iba fun Ọba Yunsa lanfaani lati wọ ibẹ.

Ṣugbọn ibinu eyi lo jẹ ki awọn tinu n bi dana sun aafin naa, lasiko wahala ọhun ni ọkan ninu awọn ọmọọba lati idile Gbolẹru si jade laye.

 

Leave a Reply