Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti tu igbimọ to n dari awọn awakọ ero nipinlẹ naa ka, inu hilahilo lawọn olugbe awọn agbegbe kan niluu Ibadan wa bayii.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọmọ ẹyin Alhaji Mukaila Lamidi ti i ṣe olori awọn onimọto wọnyi ṣe ṣigun jade sigboro tibọn–tibọn, ti wọn si ko jinijinni ba awọn araalu.
Ni kete ti Gomina Makinde ti kede pe oun ko fẹẹ ri igbimọ alaṣẹ awọn awakọ naa mọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lawọn ẹmẹwa Alhaji Lamidi, ti gbogbo eeyan mọ si Auxilliary, ti ya sigboro pẹlu ibọn nla nla, wọn n yinbọn kikan kikan bii pe wọn n bẹ loju ogun, awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn pẹlu ibẹru bojo.
Awọn agbegbe ti wahala ọhun ti bẹrẹ lati irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni Iyana-Church, Alakia, Iṣẹbọ ati Iwo-Road, ko too di pe wọn tun ṣe kinni ọhun wọ awọn agbegbe bii Apata, nigboro Ibadan, ti wọn si tun tẹsiwaju ninu ifigagbaga ibọn yinyin naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ta a wa yii.
Awọn ọlọpaa to n mojuto eto aabo nigboro Ibadan ko foju ba oorun lalẹ ọjọ Aje, moju aarọ yii pẹlu bi wọn ṣe n lakaka lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan lọwọ awọn ẹruuku naa ti wọn di kanranjángbọ́n saarin ilu.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn rukerudo lọtun-un-losi yii lo mu ki awọn ọlọpaa ṣigun lọ sile Auxiliary to wa laduugbo Alakia, n’Ibadan, nibi ti awọn ọmoogun baba naa ti fìja pẹẹta pẹlu wọn fun ọpọlọpọ wakati, ko too di pe apa awọn agbofinro pada ka wọn nigbẹyin.
Bo tilẹ jẹ pe Auxiliary funra rẹ ti fere ge e, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi ti jagunlabi sa pamọ si titi di ba a ṣe n kọroyin yii, pupọ ninu awọn ẹmẹwa rẹ lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ bayii, awọn ibọn alagbara ti wọn si ba ninu ile ọhun to ogoji (40) niye pẹlu ọpọlọpọ oogun abẹnu gọngọ.
Ta o ba gbagbe, ọrọ Alhaji Lamidi wa ni kootu, o ṣi n jẹjọ oriṣiiriṣii ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an nile-ẹjọ lọwọ.
Titi ta a fi kọ iroyin yii tan, o jọ pe awọn agbofinro n wa Auxiliary, ko si jọ pe ọga awọn onimọto naa duro nitosi, oun paapaa ti sa lọ mọ wọn lọwọ bamubamu.
Ninu fidio to tẹ ALAROYE lọwọ nipa akọlu naa ni ẹnikan ti n ṣalaye bawọn ọlọpaa ṣe ya wọn inu ile ọga onimọto naa, ti wọn fi ibọn da batani si ara awọn mọto, oju ferese ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ile ọhun.
Ọpọlọpọ mọto to wa ninu ile naa lo bajẹ, tawọn gilaasi oju windo awọn ile ọhun si fọ silẹ kaakiri.