Ajalu nla lagbo tiata: Oṣere kan tun ku lojiji

Adewale Adeoye

Ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Dayọ Adewunmi, ẹni tawọn eeyan mọ si Sule Suebebe, jade laye l’Ọjọruu, Wẹside, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii. Iyalẹnu niroyin iku ọkunrin yii jẹ fun ọpọ awọn eeyan. Idi ni pe loootọ ni ara rẹ ko ya, ṣugbọn ọkunrin naa ti n gbadun daadaa, ti awọn ololufẹ rẹ si ti ro pe o ti yi kinni naa jẹ niyẹn. Nitori ọpọ eeyan lo dide iranlọwọ owo fun un lọdun to kọja, nigba ti wọn kọko ṣafihan rẹ pe o wa lori idubulẹ asian nla kan.

ALAROYE gbọ pe ileewosan ijọba kan to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lo dakẹ si laaarọ kutukutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu yii.

Pasitọ Ademọla Amuṣan, ẹni tawọn eeyan mọ si Agbala Gabriel, ẹni to n sa sọtun-un sosi lori iwosan rẹ latigba ti oloogbe naa ti wa lori idubulẹ asian nla kan lo tufọ iku rẹ faraye gbọ lọjọ Wẹsidee  pe Oloogbe Sule Suebebe ti jade laye ni ọsibitu kan to ti n gba itọju lowọ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Bẹ o ba gbagbe, gbogbo ọna ni Pasitọ Agbala Gabriel yii gba lati jẹ ki awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ orileede Naijiria nilẹ yii ati l’Oke-Okun dide iranlọwọ owo fun un nigba to wa lori aisan. Ṣugbọn to jẹ pe aisan naa lo pada waa gbẹmi rẹ nigbẹyin.

Ẹgbẹ oṣere tiata, TANPAM, ti oloogbe naa jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ wọn ti n ba awọn ẹbi, ara, ọmọ ati ojulumọ ti oṣere yii fi silẹ saye lọ kẹdun eeyan wọn to jade laye.

Lara awọn fiimu ti Dayọ Adewumi, to tun figba kan jẹ onkọrin jujum ṣe ko too ku ni awọn bii: Ṣuku ṣuku bam-bam, ‘Pero sọkọ’,  ‘Aago kan oru’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply