Awọn agbebọn ji aṣaaju awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu APC meji lọ

Monisọla Saka

Awọn aṣaaju obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kaduna, Hajiya Lami Awarware, ati Hajiya Haulatu Aliyu, ni wọn ti ṣe bẹẹ kagbako awọn ajinigbe bayii, lẹyin tawọn olubi ẹda ọhun ji wọn gbe loju ọna Manini flashpoint, lagbegbe ijọba ibilẹ Birnin-Gwari, ipinlẹ Kaduna, ti wọn lawọn ọdaju ẹda naa ti maa n yọ awọn eeyan lẹnu.

Ninu ọrọ ti Ishaq Usman Kasai, ti i ṣe alaga ẹgbẹ itẹsiwaju ilu Birnin-Gwari sọ, o ni ibi ayẹyẹ iburawọle fun gomina tuntun nipinlẹ naa, Sẹnetọ Uba Sani, lawọn obinrin ọhun ti n bọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, tawọn eeyan ọhun fi da wọn lọna, ti wọn ji wọn gbe lọ.

O ni yatọ sawọn obinrin ẹgbẹ oṣelu APC meji yii, awọn ajinigbe ọhun tun ji ọgọọrọ awọn eeyan mi-in gbe lọ.

O tẹsiwaju pe latigba ti wọn ti ko awọn eeyan naa wọnu igbo lọ, ko sẹni to ti i gburoo wọn, nitori awọn janduku ajinigbe naa ko ti i kan si awọn mọlẹbi wọn tabi ẹnikẹni lagbegbe naa.

 

L’Ọjọruu Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lasiko tawọn mọlẹbi awọn eeyan ọhun n ba awọn oniroyin sọrọ, ni wọn rawọ ẹbẹ sijọba lati gba awọn, nitori awọn ko gburoo awọn eeyan awọn latigba ti wọn ti gbe wọn wọgbo lọ.

Leave a Reply