Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bii ọgọrin awọn oni POS ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii (EFCC), fi pampẹ ofin gbe niluu Akurẹ, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Awọn oni POS ọhun ni wọn fẹsun kan pe wọn lẹdi apo pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ banki kan lati maa ra Naira lọwọ wọn, ti wọn si n ta a lowo gegere fawọn araalu.
Ọpọ awọn kolọransi ẹda yii lọwọ tẹ lagbegbe Ọja Ọba, nigboro Akurẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, ati Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.
Awọn oṣiṣẹ EFCC yii la gbọ pe wọn n dibọn bii ẹni to fẹẹ gbowo lọwọ awọn oni POS ti wọn de ọdọ wọn, ti wọn si n fi pampẹ ofin gbe eyikeyii ninu wọn to ba ti n beere owo gegere lori owo to fẹẹ fun awọn eeyan.
Ọpọ awọn ti wọn mu ọhun ni wọn n beere ibi ti wọn ti n rowo ti wọn n ta fawọn onibaara lọwọ wọn, lẹyin eyi ni wọn yoo si tun fipa mu onitọhun lati mu wọn de ọdọ ẹni to n fun wọn lowo ti wọn n fi sita.
Ohun tawọn oni POS yooku gbọ ree ti olukuluku wọn fi tilẹkun ṣọọbu wọn nitori ibẹru awọn EFCC.