Faith Adebọla
Bo ba jẹ ọti ogogoro ti wọn ni baale ile ẹni ọdun mejidinlogoji yii, Emmanuel Kaari, mu yo lalẹ ọjọ to la ori iyawo ẹ mọ kọnkere nibi ti wọn ti n ja lo jẹ ko pa a loootọ, afaimọ lọti ọhun ko ti ran an lẹwọn bayii o, iyẹn bi ọrọ rẹ ko ba ja siku, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o pa iyawo ẹ, Florence Kaari, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, wọn lo sọ pe obinrin naa pẹ ko too wọle.
Iṣẹlẹ aburu yii waye lọjọ kẹfa, oṣu Kejila yii, lorileede Kenya, niluu kan ti wọn n pe ni Githurai.
Ninu ọrọ ti ọdọmọbinrin kan, Ruth Kaimenyi, to jẹ ọmọọdọ tọkọ-taya yii sọ ni teṣan, o ni baale ile naa ati iyawo rẹ ni wọn jọ jade lọ laaarọ ọjọ yii, ode ọtọọtọ ni wọn lọ o, amọ ọkọọyawo lo kọkọ de.
Ruth ni aajin oru ni baale ile yii de, ni nnkan bii aago mejila oru, o si ti yo bii iru nigba to fi wọle, tori niṣe lo ta gọọgọọ wọle.
Wọn ni bo ṣe wọle, iyawo rẹ lo kọkọ beere.
Ruth ni: “Bi wọn ṣe wọle, wọn beere pe nibo niyawo awọn wa, mo ni wọn o ti i wọle o, mi o si mọ’bi ti wọn lọ, lo ba ni ki n geraaotu, bawo ni mo ṣe le sọ pe mi o mọ’bi to lọ, o ni ki n lọọ wa wọn wa. Ko ju ọgbọn iṣẹju lẹyin eyi ni mọmi de, awọn ati ọrẹ wọn kan, Misiisi Gakii, ni wọn jọ wọle, mo sọ fun wọn pe ọkọ wọn ti n binu gidigidi pe wọn pẹ nita o, ọrẹ wọn si sọ fun wọn pe ki wọn ma wulẹ lọọ kanlẹkun yara ọkunrin naa, boya ki wọn sun sibomi-in di owurọ, ṣugbọn oloogbe naa ko gba, o lọọ kanlẹkun yara toun atọkọ rẹ n lo, lai mọ pe ọkunrin naa ti n rẹkẹ de e.”
Ruth tẹsiwaju pe niṣe lawọn mejeeji bẹrẹ ija laajin oru, o ni gbogbo isapa oun ati ọrẹ ọga oun yii lati pẹtu si aawọn naa lo ja si pabo, tori agbara awọn ko ka wọn. A gbọ pe ojiji ni baale ile naa si fi ori iyawo rẹ lu igun kọnkere to wa nibi kọbọọdu aṣọ wọn.
O ni ọkan ninu awọn ọmọ wọn lo sare jade waa sọ fawọn pe nnkan kan ti ṣe mọmi oun, kawọn maa sare bọ, nigba tawọn yoo si fi debẹ, ori obinrin naa ti bẹjẹ, lawọn ba sare gbe e lọ sileewosan adugbo kan ki wọn le fun un nitọju pajawiri, ṣugbọn ko pẹ to dele iwosan naa lo gbẹmii mi.
Ọmọọdọ yii ni wọn lo lọọ fiṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa teṣan Githurai 44 leti, ti wọn fi tẹle e lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn si ri i bi agbara ẹjẹ ti wọn lo jade lara oloogbe ọhun ṣe ri yamayama ninu yara naa.
Ṣa, wọn ti mu baale ile ẹni ọran yii. Ọga ọlọpaa to wa ni teṣan Kasarani, Ọgbẹni Anthony Mbogo ni afurasi ọdaran naa ti wa lakolo awọn, lọdọ awọn otẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii iṣẹlẹ ọhun.
Bakan naa ni wọn ti gbe oku Florence lọ ọsibitu ijọba fun ayẹwo, awọn si maa foju afurasi naa bale-ẹjọ lẹyin iwadii.