Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti wọ ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Lasisi Dada, lọ si ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ado-Ekiti. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe wọn ka apo nla kan to kun fun igbo mọ ọn lọwọ.
Agbefọba, Insipẹkitọ Johnson Okunade, sọ ni kootu pe lọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni ọwọ tẹ ọkunrin naa niIuu Ado-Ekiti.
Ọdaran ọhun ni wọn gba apo egboogi oloro ti wọn n pe ni igbo lọwọ rẹ lakooko ti wọn ṣe ayẹwo ẹ. Ẹsun yii ni agbefọba sọ pe o lodi sofin egboogi oloro to wa ninu iwe ofin ilẹ Naijiria, ti ọdun 1966.
Agbefọba gba ile-ẹjọ nimọran pe ki wọn fi ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn titi di akoko ti wọn yoo raaye lati ṣayẹwo si iwe ẹsun naa, ati lati ko awọn ẹlẹrii oun jọ.
Nigba ti wọn ka ẹsun naa si i leti, afurasi ọdaran naa loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Bakan naa ni Agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Stephen Ademuagun, bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn yọnda onibaara oun, o si ṣeleri pe ko ni i sa lọ, ati pe nigbakugba ti igbẹjọ ba waye ni yoo maa wa ni kootu.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ A.O. Adeọṣun faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọta Naira silẹ fun ọdaran naa, pẹlu oniduuro kan. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii.