Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lati mọkan le, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ atunto ti wọn gbe kalẹ.
O ni lai fi ti gbogbo nnkan to ṣẹlẹ ṣe, ipinlẹ Ọṣun ni ẹgbẹ oṣelu Onitẹsiwaju ti rẹsẹ walẹ ju nilẹ Yoruba, nitori naa, wọn gbọdọ wa niṣọkan lati le gbin ifẹ ẹgbẹ naa sọkan gbogbo eniyan.
Ninu ọrọ to fi ranṣẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, Oyetọla ni asiko ti to lati gbe awọn igbesẹ ti yoo mu ki ẹgbẹ naa tubọ lagbara si i.
O ni idi niyẹn ti igbimọ Ọjọgbọn Adewọle to fẹẹ ṣe atunto ẹgbẹ naa l’Ọṣun fi ṣe pataki. O ni, “Lẹyin idibo gomina ọdun 2018, abajade idibo apapọ to waye lọdun 2019 fi han pe itẹsiwaju ti ba ẹgbẹ wa.
“Lai fi ti ipenija idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022 ṣe, iye awọn ti wọn dibo fun ẹgbẹ wa ninu idibo naa pọ ju awọn ti wọn dibo fun wa lọdun 2018 lọ, eyi si fihan pe ẹgbẹ wa ṣi gbajumọ nipinlẹ Ọṣun.
“Nitori naa, a gbọdọ duro pẹlu ifẹ ti awọn araalu ni si wa, fungba diẹ ni ifasẹyin to ṣẹlẹ si wa yii, a gbọdọ ṣatunto ẹgbẹ wa ni imurasilẹ fun awọn idibo ọjọọwaju.” Bẹẹ ni Oyetọla pari ọrọ rẹ.