Monisọla Saka
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, ti tẹ obinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn (25) kan, Rahma Sulaiman, nitori bo ṣe ji ọmọ ẹ obinrin, Hafsat Kabiru, ọmọ ọdun mẹfa gbe pamọ, to si n beere owo itusilẹ toun yoo fawọn ti wọn ji ọmọ ẹ gbe sa lọ lọwọ ọkọ ẹ atijọ to bi i fun.
Muhammad Usaini Gumel, ti i ṣe Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kano, lo sọrọ naa lasiko ti wọn n foju awọn afurasi hande l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa lagbegbe Bompai, nipinlẹ Kano.
Ọdọ ọkan lara awọn mọlẹbi obinrin yii to n gbe niluu Madobi, lo mu ọmọ naa lọ, ohun to sọ fawọn yẹn ni pe oun n lọ si irinajo, yoo si gba oun lọjọ diẹ, nitori bẹẹ loun ṣe mu un wa, ki wọn le ba oun mojuto o.
Kọmiṣanna ọlọpaa yii ni ọkọ obinrin afurasi yii, Kabiru Shehu, lo fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti pe awọn ajinigbe ti gbe ọmọ oun sa lọ.
“Lọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, ọkunrin kan to n jẹ Kabiru Shehu, to n gbe lagbegbe Sharada Quarters, ijọba ibilẹ Kano Municipal, waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa pe iyawo oun tawọn ti jọ kọra awọn silẹ, Rahma Sulaiman, ẹni ọdun marundinlọgbọn, ṣalaye foun pe ọmọ oun obinrin, Hafsat Kabiru, ọmọ ọdun mẹfa, ti sọnu, ati pe awọn eeyan kan toun ko mọ ri, to ṣee ṣe ko jẹ ajinigbe ni wọn ji ọmọ awọn gbe, ati pe wọn ti n beere miliọnu mẹta Naira lati tu ọmọ oun silẹ”.
Gumel ni ninu iwadii tawọn ṣe lori ọrọ naa lawọn ti ribi wa ọmọ naa lawaari nijọba ibilẹ Madobi to wa. Lẹyin naa lawọn fi panpẹ ofin gbe obinrin tọkọ ẹ ti kọ silẹ, to jẹ iya ọmọ yii, funra ẹ lo si jẹwọ pe oun mọ-ọn-mọ mu ọmọ naa lọ sibi kan lati fara pamọ ni, koun le rowo itusilẹ gba lọwọ baba ẹ to jẹ ọkọ oun atijọ yii. O loun ko ni in lọkan lati pa ọmọ oun lara, nitori ki aṣiri ọrọ ma baa tu loun ṣe gbe e lọ sọna jinjin.
Ọga ọlọpaa yii sọ siwaju pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa.