Ijọba ti ṣafikun owo awọn agunbanirọ

Monisọla Saka

Aye ti daa de fawọn agunbanirọ ti wọn n sin ilẹ baba wọn lọwọ pẹlu bi ijọba apapọ ṣe buwọ lu ẹkunwo owo ọya wọn.

Ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin (77,000), ni wọn yoo maa san fun wọn, bẹrẹ latinu oṣu Keje, ọdun yii.

Caroline Embu, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ to n ṣeto awọn agunbanirọ, National Youth Service Corps (NYSC), lo sọrọ naa di mimọ pe ofin owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju, ti wọn ṣe loṣu Keje, ọdun 2024 yii, nijọba lo ti wọn fi fẹẹ ṣe afikun owo awọn Kọpa.

Wọn ni ọrọ yii wa ninu lẹta ti Ekpo Nta, ti i ṣe alaga ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo-oṣu ati ọwọ ọya nilẹ Naijiria, National Salaries, Incomes and Wages Commission, buwọ lu lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, to fi ṣọwọ sileeṣẹ agunbanirọ.

Ninu atẹjade ti Brigadier General Y.D Ahmed, ti i ṣe adari ajọ NYSC fi sita, lo ti dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun iwuri ti wọn fi owo naa ṣe fawọn agunbanirọ to n sin ilẹ baba wọn.

“A dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun igbesẹ ti wọn gbe, to tun waa bọ sasiko. O da wa loju pe ko ni i jẹ ohun itura nikan fawọn agunbanirọ, amọ ti yoo tun mu iwuri ba wọn lati tubọ ṣe daadaa si i ninu iṣẹ isinru ilu”.

Ki ijọba too kede afikun owo awọn agunbanirọ ni adari ajọ NYSC ti kọkọ yọju si alaga ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo-oṣu, lati le bẹbẹ fun nnkan amayedẹrun ati ẹkunwo fawọn ọdọ to n sin ilẹ baba wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ni awọn agunbanirọ n gba ki ẹkunwo yii too de.

Ọdun 2020, lẹyin ti wọn sọ owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju di ọgbọn ẹgbẹrun, ni ijọba fi kun owo awọn Kọpa lati ogun ẹgbẹrun din igba Naira (19,800), ti wọn n gba tẹlẹ.

Leave a Reply