Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Onidaajọ Adepele ti paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun Dokita Rahman Adedoyin titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.
O ni o jẹbi ẹsun mejidinlogun. Lara rẹ ni igbimọ-pọ lati huwa buburu, pipa Adegoke, hihuwa buburu si oku ọmọkunrin naa, gbigbe mọto Hilux ti wọn fi gbe oku Adegoke sọnu sa lọ si Abuja, igbimọ-pọ lati bura, igbimọ-pọ lati ji foonu, ẹrọ alaagbeletan ati pọọsi Adegoke. Igbimọ-pọ lati gbe igbesẹ ti yoo fi da bii ẹni pe Adegoke ko sun sinu oteẹli wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni wọn ni wọn tun dajọ iku fun meji ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ, Adeniyi Aderọgba, Oyetunde Kazeem.
Ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki wọn kede pe wọn n wa ọmọ rẹ Adedoyin, iyẹn Rahaman Adedoyin, to sa lọ. Wọn ni ki awọn ọlọpaa agbaye hu u jade nibikibi to ba wa.
Yatọ si eyi, adajọ tun paṣẹ pe ki Adedoyin maa san owo ileewe awọn ọmọ Timothy titi ti wọn yoo fi jade yunifasiti.
O fi kun un pe ki mọto ti wọn fi lọọ sọ oku Adegoke nu ati oteẹli rẹ di ti ijọba.
Mẹta ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ ni wọn gba itusile, ti adajọ ni wọn ko mọ ohunkohun nipa ẹsun naa. Awọn mẹta ọhun ni: Magdalen Chiefuna, Adebayọ Kunle ati Oluwọle Lawrence. Wọn sun idajọ ẹni kẹta si Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii.