Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Baale ile kan to to ẹni ọgọta ọdun, lo pade iku ojiji lasiko to n rin-irinajo lati ilu Ilọrin lọ si Eko. Ninu ọkọ ero to wa naa lọkunrin ọhun ti daku, to si gba’bẹ jade laye.
Arabinrin kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ ọhun, Abẹni Ọkin, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE ṣalaye pe ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni iṣẹlẹ naa ṣẹ, lasiko ti ọkọ ero bọọsi ọhun deede daṣẹ silẹ loju ọna maroṣẹ Ogbomọṣọ, siluu Ilọrin, nibi ti ko jinna pupọ si ilu Ọ̀tẹ́, ti awakọ si n wa mẹkaliiki ti yoo tun ọkọ naa ṣe. Lasiko naa ni baba ẹni ọgọta ọdun kan wo lulẹ ninu mọto, bẹẹ ni gbogbo awọn ero inu ọkọ n gbiyanju ati doola ẹmi baba naa, ṣugbọn pabo lo ja si, nitori ti ko si ileewosan ni arọwọto wọn, eyi lo mu ki baba naa ku.
Adari ajọ ẹṣọ oju popo ni Kwara, Federal Road Safety Corps (FRSC), Stephen Dawulung, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karunlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, sọ pe loootọ ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn nigba to jẹ pe ọrọ ilera ni iṣẹlẹ to ṣẹ ọhun, ko si ni ikapa ajọ ẹṣọ oju popo, o ni to ba jẹ pe iṣẹlẹ ijamba ọkọ ni, iyẹn lo kan awọn.