Faith Adebọla
Aṣa kan tawọn eeyan maa n da pe, ‘onigbese ti ko ba gba ẹẹmi-in fẹẹ gbẹmi ni’ ti ṣẹ mọ awọn oṣiṣẹ banki mẹrin kan lara o. Gbese ti kọsitọma kan jẹ banki wọn ni wọn lọọ sin, amọ niṣe lawọn naa jẹ gbese bọ, gbese ka-n-ka ni wọn jẹ pẹlu, tori iyawo ẹni ti wọn lọọ sin lowo ni ọrọ ṣe bii ọrọ laarin wọn, ni wọn ba ti obinrin naa lulẹ, lo ba gbabẹ ku, iṣẹlẹ naa si ti sọ awọn mẹrẹẹrin dero ahamọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ta a wa yii, o ni Abule Ijoko Lẹmọdẹ, nijọba ibilẹ Ifọ, niṣẹlẹ naa ti waye.
Wọn ni lọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni Badmus Ọlalekan, Ajibade Oludare, Femi Ọlọkọ, ati ẹni kan ṣoṣo to jẹ obinrin aarin wọn, Ẹniọla Aduragbemi, ti gbogbo wọn jẹ oṣiṣẹ banki alabọọde kan to maa n ya awọn eeyan lowo, ZEFA Microfinance Bank, to wa lagbegbe naa, lọ sile ọkan ninu awọn onigbese banki naa, wọn o ba onitọhun nile, iyawo ẹ, Vivian Omo, ẹni aadọta ọdun ni wọn ba, niyẹn ba sọ fun wọn pe ọkọ oun ti wọn wa wa ko si nile.
Wọn ni wọn ṣalaye fun iyawo yii pe gbese tọkọ ẹ jẹ banki awọn lawọn tori ẹ wa, ati pe awọn gbọdọ gba owo naa lọjọ yii, tori ọjọ gbese ọhun ti pẹ.
Iyawo yii bẹrẹ si i rawọ ẹbẹ si wọn pe boya ki wọn pada wa lọjọ mi-in ti ọkọ oun aa wa nile, tabi kẹ, ki oun jiṣẹ fun un to ba de lati yọju si wọn lọjọ keji. Amọ gbogbo arọwa yii, ẹyin igba lobinrin naa n yin agbado si, awọn oṣiṣẹ yii ni dandan ni kawọn gbowo, aijẹ bẹẹ, gbogbo dukia pataki, ati ẹrọ abanaṣiṣẹ ile wọn lawọn maa ko lọ, nigba tọkọ ẹ ba de to ba ti ri owo awọn san, ko waa gba awọn dukia naa pada, wọn lobinrin yii ni ki wọn ma ṣe bẹẹ.
Oyẹyẹmi ni niṣe lawọn oṣiṣẹ banki yii wọle ọkunrin naa, ti wọn si bẹrẹ si i ko awọn ẹrọ abanṣiṣẹ ile rẹ bii tẹlifiṣan, aayọnu, redio ati bẹẹ bẹẹ lọ, bi wọn ṣe n ko o ni iyaale ile yii n fa a mọ wọn lọwọ, to ni ki wọn ma ko awọn lẹru yii lọ, bẹẹ lo n di wọn lọwọ lati ko ẹru naa jade.
Lọgbọ-lọgbọ yii ni wọn fa lọwọ ti ọkan ninu awọn oṣiṣẹ naa fi fibinu ti obinrin naa kuro lọna, pe ko jẹ kawọn raaye ṣiṣẹ awọn bii iṣẹ, niṣe ni Vivian si fidi janlẹ yakata, lo ba daku lọọ fee.
Ere ni, awada ni, awọn aladuugbo sare du ẹmi ẹ, wọn gbiyanju lati ji i, igba ti ko tete dahun ni wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi, ibẹ ni wọn ti fidi ẹ mulẹ fun wọn pe okete eleyii ti boru mọ wọn lọwọ, obinrin ti wọn gbe wa ti jalaisi, lọrọ ba bẹyin yọ.
Ọmọ oloogbe yii obinrin lo lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Agbado, lọgan si ni CSP Awoniyi Adekunle, ti i ṣe DPO teṣan naa ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn oṣiṣẹ banki mẹrẹẹrin ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun, ni wọn ba rọ wọn da sahaamọ.
Bakan naa ni wọn gbe oku Oloogbe Vivian lọ si mọṣuari to wa lọsibitu Jẹnẹra ilu Ifọ, nipinlẹ Ogun, fun ayẹwo lati fidi ohun to ṣokunfa iku ẹ gan-an mulẹ.
CP Ọlanrewaju Ọladimeji, ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo awọn afurasi ọdaran yii lọ si ẹka ileeṣẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii ijinlẹ si iwa ọdaran abẹle (Homicide Section), lolu-ileeṣẹ wọn to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta. Ibẹ ni kaluku wọn ti n ṣalaye ohun ti won mọ nipa iṣẹlẹ naa. Ẹyin iwadii ni wọn yoo too mọ igbesẹ to kan lori iṣẹlẹ ọhun.