Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Tinubu ti tan imọlẹ sọrọ to sọ ni gbara to gba iṣakoso ijọba orileede yii lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, pe opin ti de ba owo iranwọ ori epo bẹntiroolu lakooko ijọba oun. O ni ki i ṣe loju-ẹsẹ ni igbesẹ naa yoo bẹrẹ, o di inu oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Ninu atẹjade kan tawọn alukoro eto iroyin Aarẹ fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni wọn ti sọ pe gbolohun ti Aarẹ Tinubu sọ pe ko sohun to jọ pe ijọba n sanwo iranwọ ori epo bẹntiroolu fawọn oniṣowo epo mọ ki i ṣohun tuntun rara. Wọn ni lati igba aye ijọba ana, iyẹn nigba lasiko iṣakoso ijọba Buhari ni wọn ti fopin sọrọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu naa pẹlu bi wọn ko ṣe fi sinu eto iṣuna owo ti ọdun yii rara. Wọn ni ipari oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni eyi ti wọn san fawọn oniṣowo epo naa yoo pari patapata, ti ko si ni i soore ọfẹ fawọn araalu mọ lati maa janfaani owo iranwọ ori epo bẹntiroolu gẹgẹ bo ti ṣe n waye tẹlẹ.
Awọn eeyan naa ni ki i ṣe Aarẹ Tinubu gan-an lo wọgi le eto owo iranwọ ori epo bẹntiroolu gẹgẹ bii iroyin tawọn kan n gbe kiri bayii.’
Pẹlu bawọn araalu ṣẹ n lakaka lakooko yii lati ri epo naa ra fun lilo wọn, ijọba apapọ ti sọ pe ki wọn ma ṣe kaya soke nipa ọrọ epo naa rara mọ,wọn ni laipẹ, gbogbo ohun to da bii oke iṣoro ni yoo pada wa silẹ patapata.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu ni awọn owo tawọn ijọba to ṣaaju oun n lo lati fi san owo iranwọ ori epo bẹntiroolu naa loun yoo lo fun iṣẹ idagbasoke mi-in laarin ilu, tawọn mẹkunu orileede yii gbogbo yoo si janfaani naa daadaa laipẹ.