Jọkẹ Amọri
Agbọ-sọgba-nu ni iroyin iku ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa, Murphy Afọlabi, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, awọn ololufẹ rẹ atawọn ọmọ Yoruba lapapọ. Ko sẹni to gbọ nibikibi pe oṣere naa ṣaisan kankan, koda o ṣe ọjọọbi ọdun kọkandinlaaadọta rẹ, to si gbe awọn fọto loriṣiiriṣii si ori Instagraamu rẹ lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun ta a wa yii, tawọn eeyan si n ki i ku oriire.
Afi bo ṣe di ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Karaun-un, ọdun yii, ti iroyin gba ori ayelujara pe oṣere naa ti papoda. Titi ta a fi n ṣe akojọpọ iroyin yii, ko sẹni to ti i le sọ pe ohun bayii lo fa iku ojiji ti oṣere to maa n kopa babalawo, to gbọ Ifa, to si tun mọ tifun-tẹdọ rẹ yii.
Awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lọlọkan-jọkan ti n daro iku oṣere yii. Ọkan ninu awọn to ti gbe iṣẹlẹ iku Muphy si ori ikanni rẹ ni Abiọla Adebayọ ti gbogbo eeyan mọ si Biọla Eyinọka. Oṣere naa kọ ọ pe ọjọ ‘Aiku Dudu ni eleyii o!. Ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni isinmi’.
Ọkan ninu awọn ololufẹ rẹ sọ pe, ‘haa, iku oṣere yii ba mi nibi ti ko daa, mo ṣi n wo fiimu rẹ lọwọ lori Africa Majic’.
Ọmọ bibi ilu Oṣogbo, ni oṣere to ti kopa ninu fiimu oriṣiiriṣii, ti oun naa si ti gbe ọkẹ aimọye gfiimu jade yii.
O kawe ni ileewe gbogboniṣe niluu ire, nibi to ti kẹkọọ nipa eto iba ọpọ ilu sọrọ (Mass Cmmunication).
Fiimu Ifa Olokun lo gbe oṣere naa jade, eyi to ṣe labẹ Oloogbe Dagunro.
Lara awọn fiimu ti Murphy ti kopa ni, ‘Ṣọbaloju’, ‘Wasila Coded’, ‘Queen Latifat’, ‘One Blood’, ‘Owo wu mi’, ‘Ẹjẹ mi’, ‘Idera’, ‘Four Lion’ ati bẹẹ beẹ lọ.
Ẹni ọdun mọkandinlaaadọta ni kọlọjọ too de. Ọmọ mẹta, Fathia Moyọsọrẹ, Ọlamilekan ati Okikiọla lawọn ọmọ to fi saye lọ.