Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii to lọọrin nipa awọn afurasi ọdaran bii ogoji ti wọn ko sakolo wọn laipẹ yii, agbegbe Yaba ni wọn ti fin wọn jade bii okete, ti wọn fi ri wọn mu.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ loju opo ayelujara rẹ sọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn agbofinro ikọayara-bii-aṣa, Rapid Response Squad (RRS), pẹlu iranlọwọ ajọ alaabo ipinlẹ Eko, Lagos Neighborhood Safety Corps (LNSC), bẹrẹ si i lọ kaakiri agbegbe Yaba, Jibowu ati ayika rẹ, wọn n ṣakiyesi irinsi awọn eeyan to n lọ to n bọ. Ibẹ ni wọn ti rọwọ to awọn afurasi wọnyi, wọn ni ojuko ibi tawọn janduku naa n lugọ si lalẹ ni wọn ti mu wọn.
Hundeyin ni patiroolu ti wọn ṣe yii ko ṣẹyin bawọn araalu ṣe n figba gbogbo kegbajare sawọn ọlọpaa lagbegbe naa pe ki wọn tubọ pese aabo fawọn latari ọṣẹ tawọn ọmọ toro-toro-lejo-n-rin yii n ṣe fun wọn.
Wọn ni niṣe lawọn ọmọ ganfe yii maa n lugọ de awọn ero, awọn oṣiṣẹ to n dari rele wọn lalẹ, atawọn araalu gbogbo, ti wọn yoo si ja wọn lole dukia wọn bii owo, foonu, atawọn nnkan mi-in bẹẹ.
Eyi lo mu ki Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Adegoke Fayọade, paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati bẹrẹ ifimufinlẹ, patiroolu ati iwadii ijinlẹ lawọn agbegbe tawọn ẹruuku naa ti n ṣoro bii agbọn.
Lẹyin tawọn ọlọpaa ṣayẹwo finni-finni si gbogbo awọn ogoji ti wọn mu yii, wọn ri i pe mẹsan-an ninu wọn ko mọwọ-mẹsẹ, wọn si ti yọnda wọn fawọn mọlẹbi wọn.
Awọn mọkanlelọgbọn yooku ni alaye lati ṣe niwaju adajọ, wọn si ti ko wọn sahaamọ, titi tiwadii yoo fi pari, ti wọn yoo si taari wọn si kootu gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe paṣẹ.