Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Wamuwamu lawọn agbofinro duro laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, yii, siwaju ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa ni Oke-fia, niluu Oṣogbo, eleyii ko si ṣẹyin bi idajọ yoo ṣe waye lori ẹsun ti wọn fi kan Dokita Rahmon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa lori iku Timothy Adegoke.
Oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni wọn sọ pe akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, ku sinu otẹẹli Adedoyin to wa niluu Ileefẹ.
Awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfẹẹfa ti wọn jọ n jẹjọ ọhun ni Adedeji Adeṣọla, Magdalene Chefunna, Adeniyi Aderogba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem ati Adebayo Adekunle
Oṣu Kẹta, ọdun 2022, si ni igbẹjọ bẹrẹ niwaju adajọ agba funpinlẹ Oṣun, Onidaajọ Bọla Adepele-Ojo, ti onikaluku awon agbẹjọro olujejo ati olupẹjọ sì ti sọ tẹnu won. Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni igbẹjọ pari.
Akọroyin ALAROYE ti wa ninu ile-ẹjọ giga naa lati maa fi gbogbo bo ba se n lo to yin leti. Aago mẹsan-an nireti wa pe kootu yoo jokoo.