Ọkọ oju omi kankan ko gbọdọ ṣiṣẹ lẹyin aago meje alẹ – Ijọba Eko

Monisọla Saka

Pẹlu ba a ṣe n wọnu pọpọṣinṣin ọdun lọ yii, ijọba ipinlẹ Eko ti ṣekilọ pe ofin to de awọn ọlọkọ oju omi ti wọn n na oju omi to jẹ ti ipinlẹ Eko, eyi to sọ pe wọn ko gbọdọ ṣiṣẹ kọja aago meje alẹ ko ti i yẹ, ki wọn ma si ṣe tori ọdun to n bọ sọ iṣẹ di aṣedoru.

Ninu atẹjade kan ti Adari ajọ to n ri si ọrọ aabo nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Lanre Mọjọla, Ati adari eto irinna oju omi, Lagos State Waterways Authority, (LASWA), Ọgbẹni Damilọla Emmanuel, buwọ lu, ni wọn ti ṣalaye pe ijọba ti ki awọn awakọ oju omi nilọ lati pa ofin eto irinna oju omi mọ, ki wọn le dena ijamba, ofo ẹmi ati dukia lori omi.

“Ni ibamu pẹlu ofin eto aabo irinna oju omi ti awọn alaṣẹ atawọn tọrọ kan fi lelẹ, laarin aago marun-un aabọ idaji si aago meje alẹ ojoojumọ ni awọn ọlọkọ oju omi le maa ṣiṣẹ. Iwa irufin si ni lati ri atukọ ati ero lori omi to ba ti tayọ awọn akoko ta a darukọ yii. Fun idi eyi, gbogbo awọn to n wakọ atawọn ti wọn n ṣe irinajo lori omi ni a rọ lati tẹle ofin yii, ki ijamba ta a ko lero ma baa waye.

‘‘Bakan naa lo pọn dandan fun awakọ atawọn ero ẹ lati wọ aṣọ idaabobo nigbakuugba ti wọn ba ti n gun ọkọ oju omi. Eleyii ṣe pataki nitori pe ti ijamba ọkọ ba tiẹ waye, aṣọ to nipọn pelebe ti wọn wọ lori ẹwu ọrun wọn yii ni ko ni i jẹ ki wọn ri si isalẹ omi, dipo eyi, niṣe ni wọn yoo maa lefoo lori omi fun bii iṣẹju meloo kan ki awọn ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri too de lati ran wọn lọwọ”.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe gbogbo awọn awakọ oju omi ni wọn gbọdọ ni awọn ohun eelo bii agolo ẹbu ti wọn fi n pana (fire extinguisher), apoti ti wọn n ko awọn nnkan itọju pajawiri si (first aid box), aṣọ kelebe to maa n dena ki eeyan wọ isalẹ omi lọ (life buoys) atawọn nnkan mi-in bẹẹ.

Ijọba tun gba wọn nimọran lati ri i daju pe wọn n rọ epo to to sinu ọkọ wọn ki wọn too gbera kuro ni ebute, nitori pe epo rirọ sinu ọkọ laarin agbami lewu pupọ, ki wọn si maa ṣe atunṣe ati ayẹwo awọn irinṣẹ ati ọkọ wọn loorekoore, ko ma di eyi to n pana tabi daku laarin agbami”.

 

Leave a Reply